Inu bi ṣọja, o yinbọn pa ṣọja ẹgbẹ ẹ mẹta, loun naa ba yinbọn jẹ

 Faith Adebọla

 Ileeṣẹ ologun ilẹ wa lawọn ti bẹrẹ iwadii, lati mọ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ibanujẹ kan to waye laarin awọn ọmoogun ilẹ wa ti wọn yan lati gbogun ti awọn janduku agbebọn lagbegbe Sokoto, amọ to jẹ ara wọn ni wọn pada doju ibọn kọ, wọn lawọn maa tuṣu desalẹ ikoko lori ọrọ naa.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹta yii, niṣẹlẹ naa waye. Ṣọja kan, Lance Corporal Nwobodo Chinonso, ni wọn lo ṣadeede fa ibinu yọ, lo ba wo ibọn ọwọ rẹ ṣunṣun, o tawọ si adọdọ ibọn naa, o si yin in lu ṣọja ẹlẹgbẹ rẹ, Leutanant Samuel Ọladapọ, atawọn meji mi-in.

Awọn meji ọhun ni Ọgagun to n dari ikọ wọn, Commander of the Forward Operating Base (FOB) Rabah, ni Sokoto, Command Seargent Major, Sajẹnti Iliyasu Inusa, ati ṣọja aladaani kan, Attahiru Mohammed, awọn mẹtẹẹta ọhun lo pa nifọna-fọnṣu.

Nigba tawọn ẹlẹgbẹ rẹ yooku si fi maa ṣare debẹ lati mu un, wọn ni ṣọja tori ẹ gbona sodi yii ti kọri ibọn naa si agbari ara ẹ, o diju mọri, o si yinbọn pa ara ẹ naa.

Alaroye gbọ pe awọn lọgaa-lọgaa mi-in bii Kọmanda 8 Division Garrison ati Kọmanda 26 Battalion, wa nibudo awọn ologun tiṣẹlẹ naa ti waye lọjọ yii.

Wọn ti ko oku awọn ọmoogun mẹrẹẹrin yii lọ si Usmanu Danfodiyo Teaching Hospital, fun ayẹwo.

Ọga ṣọja kan ti ko fẹẹ darukọ ara ẹ sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ iṣẹ aṣelaagun lo pin ṣọja yii lẹmi-in, o si le jẹ pe ori ẹ lo gbona, o niru iṣẹlẹ yii maa n waye daadaa laarin awọn ologun, amọ iyẹn ki i ṣe awawi fun ologun kan lati fogun ẹyin ja awọn ẹlẹgbẹ rẹ.

Ṣa, Alukoro fawọn ologun, Birigedia Jẹnẹra Onyema Nwachukwu, sọ ninu atẹjade kan to fi lede lori iṣẹlẹ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu Kẹta yii, pe ọrọ naa ṣi ru awọn loju, latari bi ṣọja to pa awọn ẹlẹgbẹ rẹ naa ṣe tun pa ara ẹ, o leyii ti mu ki iṣẹ iwadii naa takoko gidi.

O lawọn lọgaa-lọgaa nileeṣẹ ologun ti ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa, wọn si ti ba awọn ọmoogun yooku ati mọlẹbi awọn to doloogbe kẹdun.

O fi kun un pe iwadii ṣi n tẹsiwaju, o si rọ awọn ọmoogun yooku pe ki wọn ma ṣe kaaarẹ ọkan.

Leave a Reply