Iṣẹlẹ to ṣẹlẹ laipẹ yii ko ba ajọṣe emi atiyawo mi jẹ o-Wasiu Ayinde

Ọrẹoluwa Adedeji

Mayegun ilẹ Yoruba, to tun jẹ ọkan pataki ninu awọn onifuji ilẹ wa, Alaaji Wasiu Ayinde, ti sọ pe ki awọn eeyan yee gbe ahesọ ti ko lẹṣẹ nilẹ, ti ki i si ṣe ootọ ọrọ kiri nipa igbeyawo oun o. Ọkunrin ọmọ bibi ilu Ijẹbu naa ni ko si oun to ṣe oun ati iyawo oun, oun ko si sọ fun ẹnikẹni pe oun fẹẹ kọ Emmanuella silẹ gẹge bi awọn kan ṣe n gbe e pooyi ẹnu.

Ahesọ naa waye lori fidio kan to n ja ran-in lori ayelujara, nibi ti iyawo ọkunrin onifuji naa, Emmanuella to saaba maa n pe ni Ajikẹ Ọkin ti fẹẹ fi ẹnu ko ọkọ rẹ lẹnu layaajọ ọjọọbi rẹ. Ṣugbọn eyi ti Wasiu iba fi fi ifẹ han si obinrin yii, niṣe lo gbe ẹnu rẹ sa fun un, ti ko si gba ko fi ẹnu ko oun lẹnu.

Eyi lawọn eeyan ri ti wọn fi n sọ pe o da bii pe Oluaye ko nifẹẹ obinrin naa mọ, wọn ni ọkan rẹ ko si lọdọ arẹwa obinrin naa mọ, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe o ti fẹẹ kọ ọ silẹ ni.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu Kẹta yii, ni agbẹnusọ ọkunrin ti wọn tun maa n pe ni Oluaye fuji yii, Kunle Rasheed, gbe ọrọ kan jade lori Instagraamu rẹ, nibi to ti gbẹnu Wasiu Ayinde ṣalaye pe ko si ohun to jọ pe ọga awọn onifuji yii ko fẹran iyawo rẹ mọ, tabi pe o ti n mura lati kọ ọ silẹ.

Ọkunrin naa ṣalaye pe ‘‘Awọn eeyan kan ti pe akiyesi wa si ahesọ ọrọ ti ko wa lati ọdọ wa to n lọ nigboro, ti ko ṣee tẹle pe Mayegun ilẹ Yoruba, K1 de Ultimate, ati ololufẹ rẹ ko nifẹẹ ara wọn mọ, eyi lo fa a to fi kọ lati fi ẹnu ko o lẹnu lasiko ọjọọbi to fi ya a lẹnu nileetura  Radisson Blu, lopin ọsẹ to kọja.

‘‘Awọn ti wọn n gbe iborun yii kiri ti fẹẹ sọ ohun ti ko ṣe pataki, ti ko si nitumọ yii di nnkan pataki ti wọn fẹẹ yi si ibomi-in, eyi ti wọn lero pe o yẹ ki awọn maa gbe kiri, ki awọn si maa ṣajọyọ ohun ti ko ṣẹlẹ yii fun idi ti ko ye ẹnikẹni.

‘‘O jẹ ohun to ṣe ni laaanu pe ọrọ odi ti ko daa ti awọn eke adugbo to n gbeborun yii mọ lati maa gbe kiri ko jẹ ki wọn rina ri i pe ifẹ to jinlẹ lo wa laarin tọkọ-tiyawo yii ti wọn ni si ara wọn.

‘‘Ohun to han gbangba ni pe K1 ati iyawo rẹ, Emmanuella, nifẹẹ ara wọn de gongo, eyi gbọdọ ye awọn ti wọn n gbe ohun ti ko ṣẹlẹ kiri nipa tọkọ-tiyawo naa’’.

Rasheed tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ọpọ awọn ti wọn n gbeborun yii ni wọn ti kọkọ ro pe igbeyawo yii ko le tọjọ, sugbọn nigba ti wọn ri ifẹ ijinlẹ to n bẹ laarin ọkọ atiyawo yii ni ara bẹrẹ si i ni wọn. O ni ọrọ naa ko ibanujẹ ọkan ba awọn ti wọn ro pe igbeyawo naa ko ni i tọjọ debii pe gbogbo ọna ni wọn n wa lati ti ibanujẹ aye tiwọn si awọn tọkọ-tiyawo ti wọn n gbadun ara wọn yii.

O kadii ọrọ rẹ nilẹ pẹlu alaye pe awọn ololufẹ mejeeji yii ti wọ agbami ifẹ, ọkọ ifẹ si ti n gbe wọn kaakiri, wọn o si ṣetan bayii lati bọ silẹ ninu ọkọ ifẹ yii, bi ko ṣe ki wọn maa gbadun ara wọn lọ.

Eyi ni yoo jẹ igba keji ti Emmanuella fẹẹ fẹnu ko ọkọ rẹ lẹnu, ṣugbọn ti ọkunrin naa gbe ẹnu sa. Fidio kan ti kọkọ jade, nibi ti iyawo Wasiu tuntun yii ti n gbiyanju lati fẹnu ko o lenu, niṣe ni Oluaye Fuji si mu aṣọ inuju funfun kan, to fi sare nu ẹnu rẹ nu.

Leave a Reply