Ara meriyiri! Babalawọ wọṣọ oogun lọ si banki

Faith Adebọla

 Bo ba jẹ ori tẹlifiṣan tabi lori fọnran ni aworan naa ti jade ni, niṣe leeyan iba sọ pe fiimu ere ori itage ni, tori iran to ṣajeji patapata ni iṣẹlẹ naa, kọsitọma ileefowopamọ   Access Bank kan, lo dira oogun bii ẹni fẹẹ rubọ lojubọ awo, lo ba kọri si ẹka banki ọhun kan ni iyalẹta ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu Kẹta yii, o loun nilo Naira, oun fẹẹ gbowo jade ninu akaunti oun.

B’ọkunrin naa ṣe yọ ganboro si banki ọhun, niṣe lawọn eeyan bẹrẹ si i yago lọna fun un, tori ko wọṣọ gẹgẹ bawọn onibaara yooku ṣe mura, aṣọ pupa foo bii ina lo san mọdii, ko sẹwu kankan lọrun ẹ, bẹẹ lo fi ẹfun sami awo loriṣiiriṣii si oju ati ara ẹ, o so okun kan to n dan bọrọbọrọ bii ejo kọrun, o si de fila kan to jọ eyi ti awọn alawo ni ilẹ Ibo saaba maa n de.

Ọkunrin naa tun gbe igba kan ti nnkan to jọ ẹbọ wa ninu rẹ dani, o si mu ọpa ṣekele tawọn alawo maa n lo sọwọ ọtun rẹ pẹlu kaadi ATM ati gege ikọwe, lo ba dori kọ ẹnu ilẹkun abawọle sọdọ awọn oṣiṣẹ to wa lori kanta naa.

Ninu foto ati fidio ọkunrin tẹnikan o mọ orukọ ẹ yii to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, a ri i bo ṣe wọnu ilẹkun sikiọriti to wa ni banki Access naa, bẹẹ lawọn eeyan n ya fọto ẹ loriṣiiriṣii. Bawọn kan ṣe n ṣẹfẹ, ti iran naa n pa wọn lẹrin-in arintakiti, bẹẹ lawọn mi-in n fọwọ luwọ, ti wọn si n ṣaroye pe inira tijọba mu ba wọn lori ọrọ ọwọngogo owo Naira yii ti pọ ju, ohun lo si fa oriṣiiriṣii nnkan ti awọn eeyan n ṣe.

Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ ohun to ṣẹlẹ nigba ti kọsitọma ara-ọtọ yii wọle, boya o ri owo Naira gba, abi bakan naa lọmọ ṣori ni, ko sẹni to mọ.

Tẹ o ba gbagbe, oriṣiiriṣii iran awoyanu lo ti waye lawọn banki ilẹ wa latigba ti wahala ọwọngogo owo Naira yii ti bẹrẹ loṣu meji sẹyin.

Ninu ẹ ni ti genge kan to wọ banki nihooho ọmọluabi lati gba owo, bẹẹ la ti ri obinrin to wọ banki nihooho, bo tilẹ jẹ pe awọtẹlẹ wa nidii rẹ, a si ri baba arugbo to n sunkun yọbọ bii ọmọ ikoko, tori inira airowo gba ni banki ati lẹnu ẹrọ ATM.
Amọ pelu bi ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa ṣe gbe idajọ kalẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, wọn ni nina ni gbogbo owo, ati owo Naira atijọ ati tuntun, kijọba jẹ kawọn eeyan ṣi maa na gbogbo ẹ lọ na titi di ọjọ to gbẹyin ninu ọdun 2023 yii, ti awọn owo atijọ naa yoo kogba sile.

Leave a Reply