Wọn ni Wolii Salami mọ nipa iyawo ile to ku sinu ṣọọsi rẹ n’Idanre

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Wolii ijọ alaṣọ funfun kan to wa niluu Alade-Idanre, nijọba ibilẹ Idanre, Salami Kayọde, ti n ran awọn agbofinro lọwọ ninu iwadii ti wọn n ṣe lori ọrọ iku abilekọ kan, Adejọkẹ Ọlọjẹ, ẹni ti wọn ba oku rẹ ninu yara kan ni ṣọọsi ọhun lọsan-an gangan Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 2023 ta a wa yii, ti wọn si ni pasitọ naa mọ nipa rẹ.

Gẹgẹ bii iwadii t’ALAROYE ṣe lori iṣẹlẹ ọhun, ilu oyinbo ni ọkọ Adejọkẹ wa, to si gba ile aladaagbe kan fun iyawo rẹ l’Akurẹ, nibi ti wọn fi ṣe ibugbe.

Nigba to ya lo ko ẹru rẹ, to si gba ilu Idanre, lọdọ iya rẹ lọ, nibi to gbe fun bii oṣu diẹ ki ọmọ aburo baba rẹ kan ti wọn n pe ni Aderonkẹ too tun mu un lọ sile ara rẹ ni Alade, nitosi Idanre.

Aderonkẹ ọhun naa lo si ṣe ọna bi Adejọkẹ ṣe dero ṣọọsi Kérúbù àti Serafu Òkè-Ìràpadà Church of Christ, ni Alade-Idanre.

Ko sẹni to mọ ohun ti Aderonkẹ to gba iyaale ile yii sọdọ lẹyin to sa kuro lọdọ iya rẹ ri to fi le iya ọlọmọ kan ọhun sita lọsan-an kan, oru kan, o ni ki i sẹni ti oun le ba gbe ile pọ mọ.

Eyi lo mu ko ko iwọnba ẹru to n ko kiri, to si mori le ṣọọsi Wolii Salami, nibi toun ati ọmọ rẹ n sun si lati bii oṣu meji sẹyin, ko too pade iku airotẹlẹ.

O ti to bii oṣu meji to ti n sun, to n ji, ninu sọọsi naa ki iya rẹ too pada mọ pe ibẹ lo ku to fi ṣe ibugbe lẹyin to sa kuro lọdọ oun.

Nigba ti akọroyin ALAROYE ṣabẹwo si ṣọọsi ọhun, ifẹgbẹkẹgbẹ ni yara ti oloogbe n sun, nibi ti wọn ti pada ba oku rẹ ati eyi ti wolii n lo nigbakuugba to ba fẹẹ sun ninu ile-ìjọsìn. Ilẹkun wa laarin awọn iyẹwu mejeeji yii loootọ, ṣugbọn ẹnu abawọle kan ṣoṣo lo wọ awọn yara naa.

Yara Wolii Salami lo wa ninu lọhun-un, ti eyi ti oloogbe n lo si yọju sita. Ohun ta a gbọ ni pe o ti kọkọ wa a lọ sinu ṣọọsi yii bii igba meji sẹyin, igba kẹta ti yoo lọọ ṣe abẹwo si oun ati ọmọ rẹ lo ba oku rẹ nibi to n sun.

Bi Iya Adejọkẹ ṣe wọnu ọgba ṣọọsi naa lo n gbọ igbe ọmọ kékeré ti ọmọ rẹ n gbe lọwọ kíkankíkan, nigba ti yoo si wọlé lati mọ ohun to n pa ọmọ naa nigbe, oku iya rẹ lo ba to sun silẹ gbalaja lori ilẹ, ti wọn si ti bọ pata to wọ sidii de ibi itan rẹ.

Iya yii lo fariwo ta tawọn eeyan to wa lagbegbe ile-ijọsin ọhun fi mọ ohun to n ṣẹlẹ̀ gan-an.

Lara ohun to mu ki wọn fura si Wolii Salami lori iṣẹlẹ ta a n sọrọ rẹ yii ni ti sokoto to wọ lasiko naa, eyi to ja labẹ, ati ẹjẹ ti wọn ri to n jade lati oju ọgbẹ kekere kan to wa ni igi-imu rẹ, eyi tawọn eeyan fi n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe oun ati oloogbe naa wọdimu, lasiko naa niyẹn si da ọgbẹ naa si i lara.

Ninu alaye ti Iya Adejọkẹ ṣe, o ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023, ni ọmọ oun deedee ko ẹru rẹ kuro nile oun n’Idanre.

O ni gbogbo ero ọkan oun ni pe ile ọkọ rẹ l’Akurẹ lo gba lọ, lai mọ pe Aderonkẹ lo mu un tira. Obinrin naa ni ọpọlọpọ igba loun ti pe e sori aago rẹ, ṣugbọn ti ko ni i gbe e, bẹẹ ni ki i bikita lati pe oun pada.

O ni laipẹ yii loun tun gbiyanju lati pe e wo lori foonu, to si gbe e. Mama Ronkẹ ni asiko naa lo ṣẹṣẹ jẹwọ foun pe inu ṣọọsi kan ti oun ti n ṣe igbele adura loun wa ni Alade-Idanre.

Obinrin yii ni kiakia loun ti mu ọna ibẹ pọn, Adejọkẹ funra rẹ lo ni o waa duro de oun ni iyana abawọ ṣọọsi ọhun lọjọ naa ki oun le tete mọbẹ, tawọn si jọ wọle lọ.

A gbiyanju lati ṣawari Wolii Salami ka le gbọ bọrọ iku ọmọbinrin naa ṣe ṣẹlẹ. Alaye to ṣe fun akọroyin wa ni pe ṣọọbu oun, nibi ti oun ti n ṣiṣẹ wẹda, loun wa nigba ti oun gbọ nipa iku ọmọbìnrin naa.

O ni eeyan rẹ kan lo kọkọ mu wa si ṣọọsi oun lati waa kopa ninu akanṣe adura kan ti awọn n ṣe lọwọ nigba naa, lẹyin eyi lo ni Adejọkẹ pada waa ba oun pe oun niṣoro ile, ti oun si fun un ni yara kan ti yoo maa sun ninu ile-ijosin naa. Obìnrin yii lo ni oun gba sọdọ lai beere ọkọ tabi eyikeyii ninu awọn ẹbi rẹ lọwọ rẹ.

Ọpọ igba lo ni awọn maa n ṣe iṣọ-oru ti Adejọkẹ si maa n darapọ mọ awọn.

Wolii ẹni ọdun mẹtadinlogoji ọhun ni kayeefi patapata lọrọ iku obinrin naa ṣi n jẹ foun, nitori lójijì loun gbọ ariwo iya rẹ lasiko ti oun wa ninu ṣọọbu oun, eyi ti ko fi bẹẹ jinna si ṣọọsi.

Nigba ta a beere bi ọrọ sokoto rẹ to ja labẹ ati ẹjẹ to wa nigiimu rẹ ṣe jẹ, àti idi to fi jẹ iru sokoto yii lo wọ lọjọ naa.

Esi to fun wa ni pe ṣe loun mọ-ọn wọ sokoto ọhun nitori o ṣee ṣe ki oun ma lanfaani ati lo o mọ lẹyin ọjọ naa.

Nipa ti ẹjẹ to tun wa nigiimu rẹ, o ni ẹnikan lo gba oun lẹṣẹẹ nimu, nibi ti oun ti n laja laarin tọkọ-taya kan lọsan-an ọjọ naa gan-an.

Wolii Salami ni sababi lasan lọrọ iku iya ọlọmọ kan ọhun jẹ nile-ìjọsìn oun, o ni funfun lọwọ oun mọ nipa rẹ, adura to ni oun n gba ni pe ki awọn ọlọpaa le ridii ohunkohun to ṣokunfa iku obinrin naa kiakia, ki oloootọ oun ma baa ku sipo ika.

ALAROYE gbọ pe ọlọpaa atawọn ẹbi oloogbe ti n gbe igbesẹ lati gbe oku ọmọbìnrin naa lọ fun ayẹwo, nibi ti wọn yoo ti fidi ohun to ṣeku pa a mulẹ, nigba ti Wolii ati Aderonkẹ to ṣe atọna ọmọ aburo baba rẹ de ibi to ku si ṣi wa lọdọ awọn agbofinro ni olu ileeṣẹ wọn to wa l’Akurẹ.

 

 

 

 

 

 

 

Leave a Reply