Eko lawọn mẹrin yii n gbe, Ijẹbu ni wọn ti n lọọ digunjale lojoojumọ

Faith Adebọla

Beeyan ba ri awọn afurasi mẹrin wọnyi lagbegbe Mushin, nijọba Ibilẹ Oṣodi-Isọlọ, nipinlẹ Eko, ti wọn n gbe, oju ọmọluabi ati gende to lọjọ iwaju rere ni yoo kọkọ fi wo wọn, tori ọjọ-ori wọn kere, abarapa si ni wọn, amọ iṣẹẹbi lo wa lọwọ wọn, wọn kan fi ilu Eko ti wọn n gbe boju ni, iṣẹ adigunjale ni wọn n ṣe, agbegbe Ijẹbu, nipinlẹ Ogun si ni wọn ti n lọọ pawọn eeyan lẹkun lojoojumọ, kọwọ awọn agbofinro too ba mẹrin ninu ikọ ẹlẹni meje ọhun.

Orukọ awọn afurasi naa ni Ezekiel Jayesinmi, ẹni ọgbọn ọdun, oun lo dagba ju laarin wọn, Ọlaitan Ṣonibarẹ, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, Habeeb Salaudeen, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ati Ọlamilekan Tẹniọla, tọjọ ori ẹ kere ju, ẹni ọdun mejilelogun pere loun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, to sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sori ikanni wa sọ pe nnkan bii aago meji aabọ ọganjọ oru ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, ọdun yii, lawọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ wọn to wa l’Ode-Rẹmọ, gba ipe idagiri lori aago, pe awọn adigunjale kan ti n ṣe awọn eeyan bi ata ṣe n ṣe oju lagboole kan to wa lọna COTCO Road, lagbegbe naa, wọn n ja wọn lole foonu, owo atawọn dukia wọn mi-in.

Kia ni DPO teṣan Ode-Rẹmọ, CSP Ọlayẹmi Faṣọgbọn, ti ṣeto awọn ọmọọṣẹ ẹ lati lọọ koju wọn, amọ ojubọrọ kọ la fi i gbọmọ lọwọ ekurọ, nigba ti wọn si debẹ, awọn adigunjale naa gboju agan si wọn, wọn bẹrẹ si i yinbọn lu awọn ọlọpaa, bẹẹ lawọn ọlọpaa n fibọn da wọn lohun.

Nigba to ya lawọn ole naa ko sọkọ Toyota Rav-4 ti wọn gbe wa, ni wọn ba ṣina bolẹ, wọn sa lọ.

Alukoro ni pẹlu ere buruku ti wọn sa ọhun, wọn kan awọn ọlọpaa mi-in lọna lagbegbe Wárewá, wọn si da wọn duro, tori wọn ti ri apa ọta ibọn kitikiti tawọn ọlọpaa ti yin lu mọto ọhun nibi ti wọn ti n bọ, eyi si mu ki kawọn agbofinro naa fura.

Lọgan ni wọn lawọn afurasi yii fi ọkọ wọn ọhun silẹ, wọn bẹ lugbẹ, wọn si na papa bora ni Warewa. Amọ bi wọn ṣe n sa lọ lawọn ọlọpaa naa n tọpasẹ wọn lai fu wọn lara. Lẹyin ọjọ diẹ ti wọn pada sibugbe wọn ni Mushin, ọwọ ọlọpaa ti wọn n sa fun naa ni wọn pada de si, lọwọ ba tẹ mẹrin ninu wọn.

Wọn lawọn mẹrin yii ti jẹwọ pe loootọ lawọn n digun jale, meje lawọn, Eko lawọn n gbe, agbegbe ilẹ Ijẹbu lawọn ti n jale, ojooojumọ si lawọn n ṣiṣẹẹbi ọhun, bawọn ba lọ sapa oke loni-in, awọn yoo lọ sodo lọla ni.

Lara ẹru ole ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni foonu iPhone olowo nla mẹrin, Android foonu igbalode oriṣiiriṣii mẹtala atawọn nnkan mi-in.

Kọmiṣanna ọlọpaa ti paṣẹ ki wọn tete rọ wọn da sẹka tawọn ọtẹlẹmuyẹ ti n tọpinpin iwa idigunjale lolu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Eleweeran, l’Abẹokuta. Bẹẹ lo ni kawọn agbofinro wa awọn mẹta to sa lọ ọhun lawaari, tori gbogbo wọn gbọdọ kawọ pọnyin rọjọ ni kootu laipẹ.

Leave a Reply