O ma ṣe o, obinrin yii ṣubu lule lasiko to n kọrin ẹmi ni ṣọọṣi, lo ba ku

Adewale Adeoye

Ṣe lọrọ ọhun di bo o lọ yago fun mi ninu ijọ Ọlọrun kan ti wọn n pe ni, ‘Living Messiah Church’, to wa lagbegbe Agbor, nijọba ibilẹ Ika-South, nipinlẹ Delta, lasiko ti obinrin akọrin ẹmi kan, Oloogbe Imade, deede ṣubu lulẹ gbalaja lori pẹpẹ ṣọọṣi ọhun lasiko to n kọrin lọwọ, to si ku patapata lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2224 yii.

ALAROYE gbọ pe ko sohun to ṣe oloogbe naa ko too di pe o bẹrẹ si i kọrin ẹmi tawọn eeyan mọ ọn si, bo ṣe n fo soke lori pẹpẹ ṣoọṣi ọhun, bẹẹ lo n fo silẹ, to si n forin to ni imisi da awọn ọmọ ijọ ti wọn wa lori ijokoo lọjọ naa lara ya gidi. Ṣugbọn lojiji ni kinni ọhun ki i mọlẹ, kawọn ọmọ ijọ atawọn alagba inu ṣọọṣi ọhun si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Oloogbe Imade ti fidi janlẹ, lo ba ṣubu yakata lori pẹpẹ. Kọrọ ma baa bẹyin yọ lo mu ki wọn sare gbe e digbadigba lọ sinu ile kan to wa layiika ṣọọṣi naa, ṣugbọn nigba tawọn to n ṣetọju rẹ ri i pe ko tete dide ni wọn ba tun gbe e lọ sileewosan alaadani kan ti wọn n pe ni ‘Alero Hospital’, fun itọju, ṣugbọn nigba tawọn dokita maa fi ṣayẹwo si i lara, niṣe ni wọn sọ fawọn to gbe e wa pe o ti ku.

Wọn ti gbe oku rẹ si mọṣuari kan to wa lagbegbe naa

Leave a Reply