Adanu nla ni iku Ọba Ọlalekan Balogun jẹ fun iran wa – Yoruba Obas Forum

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Agbarijọpọ awọn lọbalọba nilẹ Yoruba, labẹ Yoruba Obas Forum (YOF), ti ranṣẹ ibanikẹdun si awọn eeyan ilẹ Ibadan, awọn igbimọ Olubadan atijọba ipinlẹ Ọyọ, lori iku Olubadan, Ọba Ọlalekan Balogun.

Ninu atẹjade kan ti Aarẹ apapọ wọn, Mọlokun ti Atijere, Ọba Samuel Adeoye (JP) fi sita ni wọn ti ṣapejuwe iku baba naa bii adanu nla fun iran Yoruba. Wọn ni agbọ-sọgba-nu ni iroyin naa jẹ nigba ti awọn gbọ ọ lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ‘‘Ọba Ọlalekan Balogun jẹ ọba ti asiko rẹ lori itẹ mu alaafia ati itẹsiwaju ba ilẹ Ibadan, bẹẹ lo jẹ manigbagbe laarin awọn igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọyọ lapapọ’’.

Bakan naa ni wọn sọ pe baba naa gbiyanju lori imugbooro eto ọrọ-aje lagbegbe rẹ, bẹẹ ni iṣẹ rere rẹ yoo maa tọ ọ lẹyin.

Yoruba Obas Forum gbadura pe ki Ọlọrun tẹ baba naa si afẹfẹ rere, ko si fun awọn mọlẹbi rẹ ati gbogbo ilẹ Ibadan ni ẹmi lati fi gba adanu naa.

Tẹ o ba gbagbe, Ọba Ọlalekan Balogun gun ori itẹ awọn baba nla rẹ loṣu Kẹta, ọdun 2022, o waja l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu yii, ti wọn si sin in si agboole Aliwo, niluu Ibadan.

 

Leave a Reply