Kabiesi pe ipade igbimọ Olubadan lọjọ ti wọn jade laye- Ẹkẹrin Olubadan  

 Ọlawale Ajao, Ibadan

Ẹni to ko gbogbo eeyan mọra l’Ọba Lekan Balogun. Ki i ṣe ọba paṣewaa, o maa n gba imọran lọwọ awa igbimọ rẹ. Aye ti awa igbimọ Olubadan ko jẹ ta a ba pa gbogbo asiko awọn Olubadan to ti kọja pọ, a jẹ ju bẹẹ lọ lasiko Ọba Balogun. Owo ti Olubadan maa n gba lọwọ awọn to ba fẹẹ joye, baba ki i da si i, funra wọn ni wọn sọ fun wa pe awa ni ka ro iye ta a ba fẹẹ maa gba, wọn ki i si ba wa da si ọrọ owo yẹn. Iye ti awa funra wa ba fun wọn ninu ẹ naa ni wọn maa gba. O si le jẹ pe loju ẹsẹ naa ni wọn maa fowo yẹn tọrẹ. Wọn jẹ ọba to maa n tọrẹ gan-an. Ti wọn ba gbe ẹbun aawẹ wa fun Kabiesi, ti mo ba de, ti mo gbe ninu ẹbun yẹn, ti wọn ba lọọ sọ fun baba, baba a a ni, ‘Ẹkẹrin gbe nnkan ninu ile yii, ẹ wa n fẹjọ sun mi, ki lẹ waa fẹẹ ṣe si i?’ Aarọ ọjọ ti wọn ku, awọn funra wọn ni wọn pepade, a si wa nile wọn di aago mẹta ọsan ọjọ yẹn, afi ba a ṣe dele ta a deede gbọ ni nnkan bii aago mọkanla alẹ pe baba ti waja. Ẹkọ ti mo ri kọ lara baba pọ, ṣugbọn ohun to ya mi lẹnu ju nibẹ ni pe mi o ri ibi ti wọn ti tan baba ni suuru ri.

Leave a Reply