Eyi nidi ti mi o ṣe gba awọn eeyan laaye lati maa ri Ọba Balogun mọ- Sẹnetọ Kọla Balogun 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Mo dupẹ fun igbesi aye Kabiesi ati iru eeyan ti wọn jẹ. Wọn jẹ eeyan to maa n ṣawada pupọ, ati eeyan to maa n fi nnkan tọrẹ, baba wa ni wọn fi awọn nnkan wọnyi jọ. Ko si iṣoro tẹẹ maa gbe lọọ ba wọn ti wọn o ni i yanju.

Awọn Yoruba maa n powe pe a ki i gbọ “gbe ru mi laafin”, iyẹn ni pe ọba ki i tọrẹ, awọn araalu lo maa n ta ọba lọrẹ. Ṣugbọn ti Ọba Balogun ko ri bẹẹ, awọn maa n ta araalu lọrẹ daadaa ni tiwọn. Nibi ti wọn maa n ta awọn eeyan lọrẹ de, awọn eeyan kan tun lo oore-ọfẹ yẹn lati lu wọn ni jibiti. Awọn ni Olubadan akọkọ ti mo ri to maa n fowo ranṣẹ si gbogbo idile agboole rẹ lẹẹmeji laarin oṣu kan. Iyẹn ni gbogbo ara agboole wa ṣe n sunkun nigba ti wọn gbọ iroyin pe ọba ti waja. Wọn jẹ ẹlẹyinju aanu eeyan pupọ. Nigba ti ọdun eegun fẹẹ maa la wahala lọ, niṣe ni wọn da ọdun eegun duro titi digba ti wọn fọwọ siwee adehun pe awọn yoo maa gba alaafia laaye. Ọmọ ọkan ninu awọn ijoye wọn nilo iṣẹ nileeṣẹ nla kan nigba kan, awọn funra wọn ni wọn tẹle ọmọ yẹn lọ sibẹ ti wọn fi gba ọmọ yẹn sileeṣẹ yẹn. Bi wọn si ṣe maa n ṣe si gbogbo eeyan to ba nilo iranlọwọ wọn niyẹn. Nigba ti mo wa nipo sẹnetọ, ojoojumọ ni wọn maa n pe mi lati beere alaafia mi. Iyẹn lo se je pe lọjọkọjọ ti mo ba wa s’Ibadan lati Abuja, tabi lati ilẹ okeere ti mo ba lọ, ile wọn ni mo kọkọ maa n gba lọ ni kete ti mo ba kuro ni papakọ ofurufu. Nitori bi wọn ṣe jẹ gbajumọ eeyan lawujọ, wọn mu iyi ba ipo Olubadan. Iyẹn lo ṣe jẹ pe kaakiri orileede yii lawọn eeyan ti wa sibi ayẹyẹ iwuye wọn lọjọ ti wọn gori itẹ. Ko si Olubadan ti wọn ṣe iru ayẹyẹ nla bẹẹ fun ri. Gbogbo awọn eeyan nla nla ti wọn ko ranti fiwe pe paapaa lo wa sibẹ funra wọn, titi dori Ẹmir tilẹ Kano. Gbogbo ijoye wọn ni wọn maa n fun lowo nla nla lasiko ọdun. Emi funra mi ni mo ṣeto ki awọn ti wọn yoo maa lanfaani lati de ọdọ dinku. Obìnrin kan lọọ kunlẹ siwaju wọn lọjọ kan, o ni oun nilo ẹgbẹrun lọna igba Naira lati sanwo ile oun. Bi mo si ṣe n wo obinrin yẹn, ko jọ eni to lagbara lati gba ile to to ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (₦50,000). Ọlọpaa to n ṣọ wọn fẹẹ le obinrin yẹn lọ, ṣugbọn niṣe ni baba bẹrẹ si i bu u pe ki lo de to n le e, ṣebi oun Olubadan lo wa wa. Gbogbo ipe ni baba maa n gbe. Laipẹ yii lẹnikan waa beere ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (₦150,000) lẹyin ọjọ keji ti wọn fun un lẹgbẹrun lọna irinwo Naira (₦400,0000) ni. Bi gbogbo awọn to wa nibẹ ṣe bẹrẹ si i bu baba yẹn niyẹn pe eeyan fun ẹ ni ₦400,000 lanaa, o tun wa n beere ₦150,000 lonii. Nigba ti mo ri i pe awọn to n tọrọ owo lọwọ wọn lojoojumọ ko jẹ ki wọn gbadun ni mo ṣeto ti ko fi ni i rọrun fun gbogbo eeyan lati maa ri wọn.

Leave a Reply