Ọlọrun ṣe ojuṣaaju fun Ọba Balogun- Sẹnetọ Rashidi Ladọja

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ki i ṣe gbogbo eeyan l’Ọlọrun maa n ṣe iru oore to ṣe fun Ọba Balogun fun. Mo maa n sọ fawọn eeyan pe Ọlọrun lo maa n fi ọba jẹ, paapaa, ipo ọba Olubadan tiwa nibi. Ilẹ yii naa la wa ti Olubadan kan fi waja, ti Ọlọrun fi mu Ọtun ati Balogun ti ipo ọba kan lọ laarin ọsẹ kan naa, O si ṣilẹkun anfaani fun ẹlom-in lati jọba, ẹni ti ko lero pe oun le jọba kiakia. Ki ni ẹgbọn mi nawọ si ti ọwọ wọn ko to. Wọn ṣe olukọ, wọn ṣaṣeyọri nibẹ, wọn ṣiṣẹ nileeṣẹ Shell BP, ileeṣẹ epo to tobi ju lọ ni Naijiria ati kaakiri agbaye, ẹgbọn mi ṣiṣẹ nibẹ, o yege. O dawọ le oṣelu, o dupo sẹnetọ, o wọle. O tun di Olubadan. Iyẹn ni mo ṣe maa n sọ pe Ọlọrun ṣe ojuṣaaju gbe lẹyin ẹgbọn mi, Ọlọrun ti fẹran wọn ju. Ki i ṣe gbogbo igba naa la ki i ja ninu igbimọ Olubadan o, ṣugbọn nigba ti ija ba waye, baba aa sọ pe awọn maa yanju ẹ, wọn si maa yanju ẹ loootọ. Mo ro pe mo maa ri wọn lọjọ Tọsidee yẹn ni, nitori awọn naa ni wọn pepade sile wọn, ṣugbọn wọn o le ba wa kopa ninu ipade yẹn bo tilẹ jẹ pe orukọ wọn naa la fi ṣepade ọhun.

Leave a Reply