Ko si ohun ti wọn fẹ lọjọ Tọsidee ti ki i tẹ wọn lọwọ- Olori Khalifat Lekan Balogun

Ọlawale Ajao, Ibadan

Kabiesi jẹ oniwa rere eeyan to maa n ba gbogbo eeyan ṣawada pupọ. Wọn ko wa ile aya mọya, bẹẹ ni wọn ki i di eeyan ṣọkan. Ọjọ Tọsidee jẹ ọjọ to ṣe koko ninu igbesi aye wọn. Ti wọn ba n jade nigba mi-in, wọn aa ni, ‘oni ni Tọsidee, nnkan ti mo fẹẹ lọọ ṣe nibi ti mo n lọ yii maa bọ si i’. Ootọ si ni, gbogbo nnkan ti wọn ba n wa lọjọ Tọsidee lo maa n bọ si i loootọ. Lọjọ ti wọn ṣalaisi lọkan mi lọ sibi ọrọ ti wọn ti maa n sọ nipa ọjọ Tọsidee, nigba yẹn ni mo yẹ kalẹnda wo ti mo ri i pe Ọjọbọ, Tọsidee, ti wọn faye silẹ naa ni wọn daye. Aaro wọn maa sọ mi gan-an, paapaa nipa awada ti wọn maa n ba mi ṣe, nitori eeyan o le wa pẹlu Kabiesi ki inu onitọhun bajẹ. Wọn si jẹ ẹni to lawọ. Iwọnba owo to ba ṣẹku si wọn lọwọ, wọn ṣetan lati fi i ta eeyan lọrẹ.

Leave a Reply