Wọn ti sọ tẹlẹ pe ọjọ Tọsidee lawọn maa ku- Olori Funmilayọ Balogun

Ọlawale Ajao, Ibadan

Baba jẹ ẹni to maa n ṣaanu, to si nifẹẹ gbogbo eeyan lọkan. Koda gan-an, ti awa ta a jẹ ẹbi wọn ba nilo nnkan, ti ara ita kan ba de, wọn a a ni ka jẹ ki awọn kọkọ da ara ita yẹn lohun na. Mo ti sọ fun wọn ri pe ẹ kọkọ maa da awa tile lohun na jare, wọn ni “haa, ẹ ṣaa jẹ ki n maa ṣe e fun wọn’’. Mo ro pe iyẹn gan-an l’Ọlọun fi n ṣaanu wọn, nitori ọpọlọpọ ibi ti ẹlomi-in ti kuna, Ọlọrun maa n ṣaanu wọn, awọn maa n ṣaṣeyọri nibẹ. Mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe bo tilẹ jẹ pe wọn ki i ṣe biliọnia, Ọlọrun ṣaanu wọn, wọn raye gbe, wọn raye lo, wọn ṣaye ire. Inu mi dun pe lilọ ti wọn lọ yẹn, wọn lọọ sinmi ni, paapaa, mo gbọ pe ọjọ Tọsidee ti wọn jade laye yẹn lapẹẹrẹ ninu ẹsin Islam, ati ọjọ ti wọn sin wọn, ati inu oṣu aawẹ ta a wa yii.

‘‘ Emi mọ pe ọjọ nla lọjọ Tọsidee ti wọn ku yẹn ninu igbesi aye wọn. Awọn naa si maa n sọ ọ pe ọjọ Tọsidee lọjọ ti awọn fẹran ju lọ, nitori ọjọ Tọsidee ni wọn bi awọn. Wọn si tun waa ti sọ pe lọjọkọjọ ti awọn ba maa lọ, Tọsidee naa lo maa jẹ. Emi o tiẹ ranti mọ lọjọ ti wọn jade laye pe Tọsidee lọjọ yẹn, afi nigba to di alẹ patapata, nigba yẹn ni mo too ranti pe oni ma ni Tọsidee, Furaidee ni wọn maa maa sin wọn. Ọjọ Furaidee naa ni wọn si gba ade. Emi funra mi mọ pe akanda eeyan ni wọn nitori aimọye ewu nla to ti ṣẹlẹ si wọn to jẹ pe idaji iru ẹ ki i ṣe ẹlomi-in ti wọn fi n ku. Ọwọ ti wọn fi mu awa Olori wọn jẹ nnkan ti mi o le gbagbe nipa wọn, nitori niṣe ni wọn maa n ba wa ṣere ni gbogbo igba, wọn aa bu baba wa, wọn aa bu ilu wa, wọn aa bu ọba ilu wa, wọn a ṣe gbogbo ẹ, ta a si jọ maa rẹẹrin-in. Mo ṣi ti ranti awada wọn dari laaarọ yii paapaa. Mo ranti pe oni ni Satide, to ba jẹ pe wọn ṣi wa laye ni, wọn iba ti beere lọwọ mi pe ọjọ wo loni na? Ti mo ba dahun pe oni ni Satide, wọn a sọ pe ọla ni baba ẹ, iwọ ọmọ Sunday yii.

 

Leave a Reply