Abami ẹda l’Olubadan eyi laṣiiri bo ṣe sọ asọtẹlẹ nipa ọjọ to maa ku-Olori Ọlayinka Balogun

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi oriṣiiriṣii eeyan ṣe n sọ awọn ohun ti wọn mọ nipa Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Mohood Lekan Balogun, to rewalẹ aṣa, awọn to sun mọ ọba naa pẹkipẹki ti ṣalaye aṣiri to wa nidii ọjọ ibi ati ọjọ ipapoda ọba nla ati yii ibaṣepọ ti ọjọ naa ni pẹlu bo ṣe dẹni giga laye.

Gẹgẹ bii iwadii ALAROYE, Ọjọbọ, Tọsidee, ki i ṣe ọjọ kan lasan ninu igbesi aye Ọba Balogun. Ọjọ Tọsidee lo delẹ aye, wọn ni ko si nnkan naa to nawọ si lọjọ Tọsidee ti ki i tẹ ẹ lọwọ, afi bii ẹni pe wọn fi ọjọ naa takoko igbesi aye ẹ ni.

Pabanbari ibẹ ni pe oun funra rẹ ti fi aṣiri naa pamọ si ọkan ninu awọn Olori rẹ lọwọ, o ni ọjọ Tọsidee ti oun daye naa loun maa jade laye, ọjọ Tọsidee, lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2024, si lọba naa waja loootọ, ni ibamu pẹlu asọtẹlẹ oun funra rẹ.

Bi Ọjọbọ, Tọsidee, ki i ṣee ṣe ọjọ lasan ninu aye ọba to waja yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ṣe jẹ ọjọ to lapẹẹrẹ ninu itan ọkunrin naa pẹlu. Idi ni pe bi ọjọ to gori itẹ ṣe jẹ Furaidee, lọjọ to wọ kaa ilẹ lọ paapaa ṣe bọ si ọjọ Furaidee. O gori itẹ lọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2022, o si wọlẹ sun lọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

Aṣiri yii, pẹlu ohun ti ko han si ọpọ eeyan nipa Ọba Balogun ree ninu ifọrọwerọ ti awọn ayaba kabiesi naa, aburo rẹ, pẹlu awọn agba ijoye rẹ, ṣe pẹlu pẹlu akọroyin ALAROYE n’Ibadan.

Nitori Oyinbo ẹnu ẹ to da bii ti ọbabinrin ilu Oyinbo ni mo ṣe fẹ ẹ- Olori Ọlayinka Balogun (Olori Agba)

“Oriṣiiriṣii iroyin leeyan le sọ nipa Kabiesi. Kabiesi jẹ ẹnikan to yawọ pupọ. To ba ri ẹni ti ebi n pa, a a gbe ounjẹ tiẹ fun ẹni naa. Iyẹn jẹ nnkan to maa n ṣe ni gbogbo igba. Mi o le ka iye eeyan to ti waa ba wọn fun iranlọwọ owo, ti wọn si ṣe e. Bii ki ẹnikan sọ pe oun fẹẹ sanwo sukuu ọmọ kun, ki omi-in sọ pe oun fẹẹ sanwo ile. To ba ṣe e ṣe ni, o le yọ oju ẹ fun eeyan jẹ. Kabiesi jẹ ẹnikan to mọwe daadaa. O wa lara nnkan ti mo tiẹ ṣe gba lati ba a sọrọ. nitori to ba n sọ Oyinbo bayii, bii igba ti Ọbabinrin  ilẹ Gẹẹsi n sọrọ ni. Iyẹn si jẹ ara nnkan ti mo fẹran nipa rẹ. Ki Kabiesi too ṣe tara ẹ, o maa n kọkọ ṣe ti ara ita na. Iyẹn jẹ ara ẹkọ ti mo kọ lara ẹ. Gbogbo aye lo mọ ọn si alaaanu eeyan. Bẹẹ lo tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan”.

Leave a Reply