Muhammad mura bii obinrin, o fẹẹ wọnu ile awọn akẹkọọ-obinrin ni Kano

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ajọ sifu difẹnsi ‘Nigeria Security And Civil Defence Corp’ (NSCDC), ẹka tipinlẹ Kano, ni Ọgbẹni Muhammad Munzali, ẹni ọdun marundinlogoji, to n gbe lagbegbe Kaura-Gidan-Damo, nijọba ibilẹ Shanono, nipinlẹ Kano, wa bayii. Ohun to gbe e debẹ ni pe o mura bii obinrin lati wọnu ọgba ile tawọn akẹkọọ obinrin n gbe lagbegbe naa.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹwaa aṣaalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni Muhammad wo aṣọ ẹlẹhaa kan lati fi boju, to si n gbiyanju lati wọnu ọgba ile tawọn akẹkọọ obinrin ọhun n gbe ti wọn n pe ni ‘Skyline University’, to wa lagbegbe Sardauna Crescent, ni Basarawa, GRA, Kano. Lara awọn ẹru ofin ti wọn ba lara ọdaran ọhun ni oogun atawọn nnkan mi-in.

Alukoro ajọ NSCDC, Ọgbẹni Abdullah to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ ọhun kan ni wọn ṣakiyesi pe irin ẹsẹ rẹ ko mọ, ati pe Ọlọrun to maa mu un lo ni ki wọn pe e lati fọrọ wa a lẹnu wo.

O ni, ‘Ọdọ wa ni ọdaran ọhun wa, a n ṣewadi nipa ẹsun ta a fi kan an lọwọ. A ko le sọ koko ohun to waa ṣẹ ninu ile awọn obinrin ọhun, ṣugbọn a mọ daju pe iṣẹ ibi lo fẹẹ waa ṣe nibẹ kọwọ too tẹ ẹ.

Ọga agba patapata fun ajọ ọhun, Ọgbẹni Mohammed Falala, rọ awọn araalu gbogbo pe ki wọn maa woye ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe wọn, ki wọn si tete ke sawọn agbofinro bi wọn ba rohun to ṣajoji layiika wọn.

Leave a Reply