Kayeefi: Wọn ji alaga ẹgbẹ PDP gbe sa lọ

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ, inu ahaamọ awọn ajinigbe ni alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Edo, Ọgbẹni Tony Aziegbemi, wa. Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni ọwọ awọn janduku ọhun tẹ ẹ lasiko to n bọ lati ibi ipade pataki kan to lọọ ṣe pẹlu Gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Godwin Obaseki, eyi to waye niluu Benin/

Ṣa o, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ko ti i sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ naa ti fidi iṣẹlẹ ijinigbe ọhun mulẹ pe ootọ ni wọn ji alaga ẹgbẹ PDP gbe sa lọ.

ALAROYE gbọ pe awọn oniṣẹ ibi ọhun ko ti pe mọlẹbi ọkunrin yii lati sọ ohun ti wọn fẹẹ gba ko too di pe wọn maa ju ọkunrin naa silẹ lahaamọ wọn to wa.

Atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ naa, Ọgbẹni Chris Nehikhare, fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lo ti sọ pe awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ naa ti n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lati gba alaga ẹgbẹ PDP ọhun silẹ lahaamọ awọn ajinigbe.

O ni, ‘’Loootọ ni awọn janduku kan ta a le pe ni ajinigbe dena de alaga ẹgbẹ PDP ipinlẹ wa, ibi ipade pataki kan to waye laipẹ yii laarin awọn oloṣelu ipinlẹ yii ati Gomina Obaseki lo ti n bọ ko too di pe wọn ji i gbe sa lọ. Iwadii ti n lọ labẹnu lati gba alaga naa pada layọ ati alaafia, a n fi asiko yii rọ awọn araalu gbogbo pe bi wọn ba lohun kan to le ran wa lọwọ nipa ọrọ ọhun, ki wọn tete waa sọ fun wa ka le tete ri awọn oniṣẹ ibi ọhun mu.

Leave a Reply