Wọn ti mu Ojo to n dibọn bii alaarun ọpọlọ, aṣe adigunjale ni

Adewale Adeoye

Teṣan ọlọpaa agbegbe Isọkoko, ni Agege, nipinlẹ Eko, ni Ọgbẹni Ọlasẹinde Ojo ti wọn mu fun ẹsun pe o n dibọn bii ẹni ti ko gbadun, ti arun ọpọlọ n yọ lẹnu, ṣugbọn ti nnkan kan ko ṣe e. Adigunjale paraku ni, o si ti fi ọgbọn buruku yii ja awọn olugbe agbegbe Agege, lole dukia wọn kọwọ too tẹ ẹ ni ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

ALAROYE gbọ pe ṣe ni Ojo maa n lọ kaakiri pẹlu aṣọ to dọti ati iru to ti takoko mọ ọn lori, ti yoo si maa ṣe bini were, eyi to fi n ja araalu lole.

Alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa orileede Nigeria A.C.P Olumuyiwa Adejọbi, to sọ aṣeyọri tawọn ọlọpaa ni kaakiri orileede yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu yii, sọ pe lara pe awọn ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ko fọwọ yẹpẹrẹ mu eto aabo lo jẹ ki wọn ri Ojo to n ṣe bii alaaganna ṣugbọn to jẹ pe ogboju adigunjale ni mu.

Atejade kan ti Adejọbi fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lo ti sọ pe, ‘‘Kaakiri igberiko ati origun mẹrẹẹrin orileede yii ni awọn ọlọpaa orileede yii ti ṣiṣẹ takuntakun, wọn fọwọ ofin mu ọkunrin kan to n jẹ Ojo, laipẹ yii, lagbegbe Isọkoko l’Agege Ọdaran paraku ni, ṣe lo maa n ṣe bii alarun ọpọlọ, ta a si ja awọn araalu lole dukia wọn, ṣugbọn ọwọ ọlọpaa agbegbe naa tẹ ẹ laipẹ yii, ti wọn si ti ju u sahaamọ wọn. Iwadi nipa rẹ n lọ lọwọ, awọn ọlọpaa si maa too foju rẹ bale-ẹjọ.

Leave a Reply