O doju ẹ, awọn agbebọn tu ji araalu mẹrinla gbe sa lọ nipinlẹ Kaduna

O doju ẹ, awọn agbebọn tu ji araalu mẹrinla gbe sa lọ nipinlẹ Kaduna

Adewale Adeoye

Paroparo ni gbogbo ilu kekere kan ti wọn n pe ni Dogon-Noma-Unguwan-Gamo, to wa ni Wọọdu Maro, nijọba ibilẹ Kajuru, nipinlẹ Kaduna, da bayii. Ohun to fa a ti ilu naa fi di ahoro ni tawọn agbebọn ti wọn ya wọbẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ti wọn si ji awọn araalu mẹrinla gbe sa lọ.

Awọn agbebọn ọhun ko ti i pe ijọba ipinlẹ naa lati sọ ohun ti wọn fẹẹ gba ko too di pe wọn maa tu awọn ti wọn ji gbe silẹ.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ Satidee ọsẹ to kọja yii, ni iṣẹlẹ ọhun waye. Ibọn ni awọn oniṣẹ ibi naa bẹrẹ si i yin ni gbara ti wọn denu ilu naa. Ṣe ni ipaya nla gbọkan awọn eeyan ilu yii pẹlu iro ibọn ti wọn n gbọ lakọlakọ. Ọta ibọn ti awọn ajinigbe ọhun n yin bo ṣe wu wọn lo lọọ ba awọn eeyan kan, ti wọn si fara pa yannayanna. Oju-ẹsẹ ni wọn ti sare gbe wọn lọ sileewosan, ti wọn si n gba itọju lọwọ titi di ba a ṣe n sọ yii.

Awọn mẹrinla ni wọn ji gbe sa lọ niluu ọhun lasiko laaṣigbo naa, ninu eyi ti obinrin marun-un wa.

Ọgbẹni Stephen Maikori to sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun sọ pe lojiji lawọn agbebọn ọhun ya wọnu ilu naa wa. ‘’A ko mọ ohun ta a ṣe fawọn agbebọn ọhun bayii, ṣugbọn o daju pe ko seto aabo mọ lorileede yii, nitori pe fun ọpọlọpọ wakati lawọn agbebọn ọhun fi ṣoro, ti ko si si iranlọwọ kankan lati ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe ọhun titi ti wọn fi ṣiṣẹ buruku naa tan, ti wọn si sa lọ’’

Bẹẹ o ba gbagbe, ko ti i ju oṣu mẹrin lọ, nitori ninu oṣu Kejila, ọdun to kọja yii, ni awọn agbebọn ọhun waa kogun ja wọn niluu ọhun. Inu oṣu Kẹta, ọdun yii, ni wọn too ko gbogbo awọn araalu ti wọn ji gbe lasiko naa silẹ lẹyin ti wọn gbowo itusilẹ ati ọkada mẹta lọwọ ẹbi awọn  ti wọn ji gbe lasiko naa. Eyi lo jọ pe o dun mọ wọn ti wọn fi tun pada wa siluu naa lọjọ Abamẹta lati ko awọn mẹrinla lọ.

Eyi lo fa a ti ọpọ awọn araalu ọhun fi n sa fi ilu silẹ, ti gbogbo rẹ si da paroparo bii ode Oro.

Leave a Reply