Idajọ oju-ẹsẹ, awọn araalu binu dana sun afurasi adigunjale kan

Idajọ oju-ẹsẹ, awọn araalu binu dana sun afurasi adigunjale kan

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ, ko sẹni to mọ orukọ gende-kunrin kan ti wọn dana sun fẹsun idigunjale kan lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lagbegbe Ikpa Road, niluu Uyo, nipinlẹ Akwa-Ibom.

ALAROYE gbọ pe awọn araalu ọhun ni wọn ṣedajọ lọwọ ara wọn nigba ti wọn mu ole naa, ti wọn si lu u bajẹ. Ẹnu lilu ọhun ni wọn wa tawọn kan fi lọọ gbe epo bẹntiroolu wa, ti wọn si da a si i lara, wọn kina bọ ọ, wọn si jo afurasi adigunjale naa deeru.

Gbogbo bi ole ọhun ṣe n japoro iku lawọn araalu ọhun n lẹ ẹ loko, ti awọn kan si tun n da epo si i lara ko le jona daadaa.

Ọkunrin kan, Ọgbẹni Okoro Chinemerem, ṣalaye pe o pẹ ti ole naa ti n lọ kaakiri igberiko, paapaa ju lọ lagbegbe Ikpa, ti yoo si ja awọn araalu ọhun lole dukia wọn, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ laipẹ yii, ti wọn si dana sun un loju-ẹsẹ ko too di pe awọn ọlọpaa de lati waa gba a silẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe naa ti lawọn maa too bẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ ọhun, tawọn si maa jabọ fawọn araalu laipẹ.

Leave a Reply