Faith Adebọla
Ṣinkin ni inu awọn ọlọja to n ṣe oriṣiiriṣii okoowo wọn ninu ọja kọmputa nla ti wọn pe ni Computer Village, n’Ikẹja, ipinlẹ Eko, n dun lasiko yii. Ohun to si ba idunnu wa ni pe ifa wọn fọ’re, ile-ẹjọ ti paṣẹ pe ki Abilekọ Fọlaṣade Tinubu-Ojo ti wọn fi joye Iyalọja-Jẹnẹra ilu Eko atawọn ọmọọṣẹ ẹ ma ṣe bu owo tabi gba owo ọja kankan lọwọ awọn ontaja Computer Village mọ, bẹẹ ni ko gbọdọ loun faini ẹnikẹni lọja naa, wọn lawọn o fọwọ si i.
Adajọ Yetunde Pinheiro tile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Ikẹja lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Ẹti, Furaidee yii, lẹyin bii ọdun kan ti wọn ti wa lẹnu igbẹjọ ati awijare lọtun-un losi lori ẹjọ naa.
Ninu iwe ipẹjọ ti nọmba rẹ jẹ ID/9039MFHR/19, nibẹ lawọn ẹgbẹ kan to n ṣoju fawọn olokoowo kọmputa, foonu atawọn ẹrọ igbalode ti wọ Abilekọ Tinubu-Ojo, ti i ṣe ọmọ bibi agba oloṣelu ilu Eko nni, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lọ sile-ẹjọ, wọn ni kilẹ-ejọ bawọn da si i, to ba tọna pe ki Tinubu-Ojo fipa yan babaọja ati Iyalọja le awọn lori, tawọn yẹn si tun ni dandan ni kawọn maa san owo ọja, owo idagbasoke atawọn faini kan ti wọn bu le awọn lori.
Awọn ti wọn tun pe lẹjọ papọ ni Abilekọ Bisọla Azeez, Ọgbẹni Adeniyi Ọlasọji, Ọgbẹni Nọfiu Akinsanya, Ọgbẹni Tony Ikani ati kọmiṣanna ọlọpaa Eko. Abilekọ Bisọla ati Ọgbẹni Ọlasọji yii ni wọn lọmọ Tinubu fi sipo Iyalọja ati Babalọja ọja nla naa.
Ẹgbẹ awọn olokoowo kọmputa, Registered Trustees of Computer and Allied Products Dealers Association of Nigeria to ṣaaju awọn ẹgbẹ yooku bii ẹgbẹ awọn onifoonu, ẹgbẹ awọn olounjẹ ati ipapanu, ni wọn pẹjọ naa lọdun 2020, wọn lawọn ti n sanwo sapo ẹgbẹ awọn, ko tun yẹ k’iyalọja kan tun wa nibi kan to maa maa beere owo lọwọ awọn, ati pe awọn kọ lawọn yan iyalọja ati babalọja naa, awọn o si mọ si i.
Lẹyin ọpọ atotonu, adajọ naa sọ pe ko tọna, ko si bofin mu rara, fun Iyalọja Jẹnẹra, tabi ẹnikẹni to yan sipo lati maa gbowo eyikeyii lọwọ awọn ọlọja, o niru owo bẹẹ ti wọn ti gba ko yẹ, owo aitọ ni, wọn o si gbọdọ tun ṣe bẹẹ mọ.
Bakan naa nile-ẹjọ ni kawọn ti wọn yan sipo Iyalọja ati Babalọja fun ọja Computer Village yii ma pera wọn bẹẹ mọ, wọn o si gbọdọ gbowo lọwọ ẹnikẹni, bẹẹ ni wọn o gbọdọ lawọn n bu faini fẹnikan lori aṣẹ ile-ẹjọ ọhun.
Ọgbẹni Timi Famọrọti, alaga ẹgbẹ awọn olokoowo kọmputa, naa ti fesi sidaajọ yii, o lo dun m’awọn gan-an, o si rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa atawọn oniṣowo ọjaa lati tete fẹjọ ẹnikẹni to ba fẹẹ dun mahuru-mahuru mọ wọn sun, kawọn le gbe igbeṣẹ to yẹ lori onitọhun.