Faith Adebọla
Ija tawọn ẹgbẹ onimaaluu ati olounjẹ lawọn n ba ijọba ja lori bawọn Hausa ṣe padanu dukia wọn nigba iṣẹlẹ Ọja Ṣaṣa to waye laipẹ yii n’Ibadan ti gba ọna mi-in yọ, ki i ṣe pe wọn o jẹ ki ounjẹ ati maaluu wọle silẹ Yoruba nikan ni, awọn orileede to mule gbe Naijiria ni wọn n ko awọn ounjẹ wọn lọ bayii.
Akọwe ẹgbẹ Northern Consensus Movement, Ọgbẹni Abdullahi Aliu, fidi eyi mulẹ ninu atẹjade kan lori iṣẹlẹ ọhun, o ni ko sohun tawọn olokoowo maaluu ati nnkan jijẹ maa padanu pẹlu ipinnu wọn yii, tori awọn ti ṣeto bi wọn ṣe maa lọọ ta awọn ọja wọn sorileede Nijee ati Cameroun, atawọn orilẹ-ede to mule gbe wọn nitosi Oke-Ọya.
Aliu ni “Bi mo ṣe n sọrọ yii, awọn eeyan ti n ko ata, tomato, alubọsa, iṣu atawọn ounjẹ mi-in lọ sawọn orileede yii, ọja wọn si n ta gidi. Idaṣẹ silẹ ta a gun le ti bẹrẹ, o si fidi mulẹ gan-an. Gbogbo ọna teeyan le fi gbe awọn ounjẹ kọja sapa ibomi-in lorileede yii lati Oke-Ọya la ti di pa, a o si ni i jẹ kẹnikẹni ko ounjẹ wọ’bẹ lati ilẹ Hausa.”
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, latigba ti ẹgbẹ awọn onimaaluu, Miyetti Allah Cattle Breeders Association of Nigeria, ti fun ijọba apapọ ni gbedeke pe ki wọn san owo to fẹrẹ to biliọnu marun-un naira (N4.7b) fawọn Hausa tawọn janduku dana sun’le, ṣọọbu ati ọja wọn nigba rogbodiyan Ọja Ṣaṣa, lẹgbẹ naa ti sọ pawọn o ni i jẹ ki ounjẹ ati maaluu kọja si agbegbe ilẹ Yoruba ati Ibo, ilẹ Hausa ni wọn maa maa duro si titi tijọba yoo fi da awọn lohun. Bakan naa ni ẹgbẹ apapọ awọn olokoowo ounjẹ ati onimaaluu lawọn ti daṣẹ silẹ, awọn o ni i gbe ounjẹ kọja silẹ Yoruba mọ.
Lati ọjọ Tọsidee, Ọjọbọ to kọja yii, lawọn ọdọ Hausa kan ti bẹrẹ si i gbe’gi dina fawọn tirela ti wọn n ko awọn nnkan jijẹ bọ lati apa Oke-Ọya, wọn o si jẹ ki wọn ko awọn ọja naa kọja, ilu Jẹbba to wa lẹnu aala ipinlẹ Niger ati Kwara ni wọn da awọn ọkọ naa duro si.