Njẹ ẹ gbọ pe wọn ti pa Stella Okolie, obinrin olukọni kan ni ile-ẹko giga ti Binni. Mọto lo pa a. Mọto ti Anu Adisa n wa ni. Awọn ọlọpaa lo n le mọto naa lọ, afi bara to ya ba obinrin naa nibi to duro si pẹlu ọkọ rẹ ati ọmọ wọn kan, lo ba pa a lẹsẹkẹsẹ.
Ilu Ibinni lọrọ naa ti ṣẹlẹ, loju ọna to lọ si Eko lati Binni, nibi ti obinrin olukọni yii ni ṣọọbu to ti n ta miniraasi ati omi si. Awọn onibaara rẹ lo waa ja ọja fun un, n lo ba duro siwaju mọto wọn lo n ka owo fun wọn. Oun ko mọ pe Anu Adisa to n wa mọto bọọsi kan ti ni wahala pẹlu awon ọlọpaa, ti ọlọpaa kan si ti ko sinu mọto ẹ, ti awọn to ku n le e bọ. Bẹẹ ọgọrun-un Naira ti wọn maa n gba nibẹ ti ko fun wọn ni wọn ni wọn n tori ẹ le e. Nibi ti eyi to wa ninu mọto pẹlu ẹ ti n du siarin mọ ọn lọwọ ni nnkan ti daru, nitori ọwọ mọto yi biripe lọwọ Adisa, apa rẹ ko si ka a mọ, iyẹn ni mọto naa fi ba ere buruku kọ lu Stella ati ọmọọṣẹ rẹ.
Bi Stella ti n kawo fun awọn ọlọja rẹ, bẹe ni ọmọọṣẹ rẹ n gbe ọja ti wọn ko wa wọ ṣọọbu wọn. Ohun t iwọn n ṣe ree t i mọto Adiosa t iawọn ọlọpaa n le fi ya ba wọn, to si pa Stella. Ọsibitu iwon sare gbe Ọ̄ọọṣe re yi na alọ, ooun ṣi w anib ito it n gatọju. Ọmọ obinri naa kan, Tega,ni ẹbi awọn ko ni i gba eleyii o, pe awọn ọlọpaa to pa iya oun gbọdọ jiya labẹ ofin.