Ibọn meji lawọn ọlọpaa gba lọwọ awọn ọmọ ‘Yahoo’ n’Ilaro

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu kẹta yii, ni ajọ EFCC mu awọn ọmọ ‘Yahoo’ mẹtadinlọgọta (57), n’Ilaro, ipinlẹ Ogun, ohun to si jẹ ijọloju fọpọ eeyan ni ibọn meji ti wọn ba lọwọ wọn.

Ọgbẹni Wilson Uwujaren, ọga alukoro EFCC lo fi atẹjade to ṣalaye iṣẹlẹ yii sita lọjọ Jimọ naa. Ohun to sọ ni pe awọn otẹẹli bii Yewa Frontier Hotel & Resort, Ellysam Hotel & Suits, April Suits ati IBD International Hotels lawọn ti lọọ ko awọn ọmọ Yahoo yii, Ilaro ni awọn otẹẹli naa wa.

Awọn ẹsun bii fifi ọrọ ifẹ lu jibiti lori ayelujara, fifi ọgbọn alumọkọrọyi gbowo lọwọ awọn eeyan lori intanẹẹti ni wọn tori ẹ mu awọn gende naa.

Nigba tọwọ ba wọn ni wọn ba ibọn meji lọwọ awọn kan ninu wọn.

Yatọ si ibọn meji yii, awọn mọto igbalode mẹrin tun wa ninu ohun ti wọn gba lọwọ awọn eeyan naa.

Foonu oriṣiiriṣii, kọmputa alaagbeletan atawọn iwe ọlọkan-o-jọkan ti wọn fi n lu jibiti ni wọn tun ri gba lọwọ wọn.

Bayii ni awọn EFCC to orukọ awọn gende oniyahoo naa: Ọlatunji Ọpẹyẹmi, Akintunde Michael Oluwashọla, Babatunde Gbọlahan, Emmanuel Oluwadamilare, Ogundare Adewunmi, Popoọla Salmọn, Adebayọ Tọheed Ọlamilekan, Bakare Kudus, Michael Moyọsorẹ, Ọlatunji Tosin, Ishọla Wasiu, Ugwu Ekenedelichukwu David, Salaudeen Rọqueb, Ọbafunmilayọ David, Jimọh Fatai Abiọdun, Idowu Adeọla, Ọladipupọ Nurudeen, Ọlaṣoju Mohammed, Onipẹde Tọheed, Bello Abdullahi, Ọlatunji Abiọla, Ogunbayọ Peter, Adeyẹmi Abraham Ismail, Tọheed Oluwaṣeun, Abiọla Mutiu, Shonẹyẹ Idowu, Badmus Farouk Kayọde, Ilyas Abubakri Ọlanrewaju, Ọladeji Basit Babatunde ati Ijiọla Sọliu Adewọle.

Awọn yooku ni: Ọdewunmi Samuel Pẹlumi, Oyeniyi Tẹslim Ọlashile, Shogbamu Olatunbọsun Lukeman, Adebanji Timilẹhin Michael, Bangboṣe Jonathan Ọlakunle, Ashore Damilare Godwin, Bello Tobilọba Abdullahi, Ogundeji Babaji Ibrahim, Bashir Ayodeji Tọheed, Ọlaleye Biọla Farukdeen, Sunday Ọṣunaiki Emmanuel, Adebọwale Taofeeq Ọlamilekan, Babajide Oluwapẹlumi Bọlaji, Oluyide Ridwan Ọlawale, Abdullahi Umar Farouq, Ọpẹloyẹru Kẹhinde Abdulwaheed, Adeọla Oluṣẹgun Israel, Shittu Ganiyu Ọlamilekan, Abdullahi Narudeen Owolabi, Ganiyu Kudus Ọlawale, Biọdun ỌkẸowo Sunday, Aiyemidọtun Moses Ọmọlade, Alade Hammed Oluwatosin, Ọladele Dọlapọ Temitọpẹ, Ogunrinde Gbenga Akanbi, Awobaju Kọyinsọla Damilare ati Bello Uthman Ọlayitan.

Wọn yoo gbe wọn lọ si kootu laipẹ gẹgẹ bi ọga akede EFCC naa ṣe sọ.

Leave a Reply