Awọn janduku kọ lu eégún Olóòlù n’Ibadan, eeyan marun-un ni wọn pa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Eeyan marun-un ni wọn pa nífọnná-fọnṣu nigba tawọn ọmọ iṣọta kọ lu Olóòlù, àgbà eégún ilu Ibadan, nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.

ALAROYE gbọ pe lasiko ti eégún náà n ṣe ètùtù ọlọdọọdun to máa n ṣe lọwọ lawọn tọọgi ya bo oun atawọn ọmọ ẹyìn ẹ̀ laduugbo Òjé, n’Ibadan.

O ti fẹẹ pari etutu ọhún lawọn ọmọ iṣọta naa ti wọn fẹẹ tó ọgọrin (80) niye ya dé pẹlu ibọn ada, kùmọ̀, eegun ẹran nla nla ati oriṣiiriṣii awọn nnkan ìjàmbá mi-in, tí ọrọ sì di bó-ò-lọ, yàgò lọ́nà.

Yatọ s’awọn marun-un ti awọn ipata wọnyi yìn nibọn, ti wọn sì kú loju ẹsẹ, Ọlọrun lo mọ iye èèyàn tó ṣee ṣe kó tún padà gbẹ́mì-in mi lẹyin ikọlu ọhun ninu awọn ọmọ ẹyin eegun naa.

Ìdí ni pé ọpọ eeyan lo fara gbọgbẹ nla, ti wọn sì n ti ileewosan kan gbe lọ sí òmí-ìn, ṣugbọn ti ko sí ẹni tó lè sọ ẹni tó máa kú tabi yè ninu wọn.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Aarẹ ẹgbẹ àwọn ọdẹ Sọ̀lúdẹ̀rọ̀ jake-jado ilẹ Yorùbá, Ọba Wahab Ajijọla-Anabi, ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ naa ṣoju ẹ̀ fìdí ẹ̀ mulẹ pe wọ́ọ́rọ́wọ́ leto ti agba eegun naa n ṣe n lọ ko too di pe awọn ọmọ iṣọta naa ya de toguntogun lai jẹ pe eegun tabi awọn ọmọ ẹyin ẹ kankan tọ wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Lọdọọdun l’Olóòlù máa n ṣètùtù yẹn, to máa n gbẹ́bọ kaakiri igboro Ibadan lati wúre fún gbogbo ipinlẹ Ọyọ pe kí ilu le máa rójú, ki alaafia sí máa jọba. Lẹyin ètùtù yẹn ni wọn ṣẹṣẹ máa mú ọjọ ti ọdun eégún máa bẹrẹ n’Ibadan. Eegun Olóòlù naa lo maa n jade gbẹyin lẹyin ti gbogbo eegun ba jade tan lasiko odun eégún.

“Pẹlu bi mo ṣe foju wo awọn tọọgi yẹn, wọn tó ọgọrin (80). Olóòlù ti lọ kaakiri gbogbo ibi to yẹ kó dé gẹgẹ bíi iṣe ẹ̀ lọdọọdun. O ku diẹ ko pari eto yẹn lawọn tọọgi yẹn kọ lu u laduugbo Òjé, n’Ibadan, pẹlu ọpọlọpọ ibọn, ada, àpólà igi atawọn nnkan ija oloro mi-in.

“Ọmọkùnrin kan ti wọn n pe ni Star Boy lo ṣaaju awọn tọọgi yẹn. Niṣe ni wọn n yinbọn lákọlákọ, ti wọn sì tún ju òkò ati igi, ṣugbọn kò sí nnkan kan to de ọdọ Olóòlù ninu gbogbo nnkan ìjà wọnyẹn.

“O pẹ ti ọmọkùnrin ti wọn n pe ni Star Boy yii ti maa n huwa idaluru. Oun lo pa ààfáà wá kan nitori ọrọ tíkẹ́ẹ̀ẹ̀tì mọ́tò nitori ọmọ ẹyin Auxiliary (ọga ẹgbẹ awọn awakọ ni ipinlẹ Ọyọ) ni.

‘‘Lanaa (ọjọ keji ikọlu akọkọ lawọn tọọgi yẹn tun bẹrẹ si i lọọ ka awọn eeyan mọle. Wọn lọọ ka Iyalọja Oje mọ ṣọọbu ẹ, wọn ni awọn maa dana sun un.

“Emi ni mo pe awọn ọlọpaa ti wọn fi waa kòòré àǹbílíì.  Ọpẹlọpẹ DPO Agugu ni ko jẹ ki wọn rí iya yẹn dana sun. Koda, awọn tọọgi yii tun lẹko mọ awọn ọlọpaa.”

ALAROYE gbọ pe awọn eleto aabo ijọba ipinlẹ Ọyọ ta a mọ si Operation Burst naa sare lọọ kun awọn ọlọpaa lọwọ ninu akitiyan wọn lati pẹtu sí làásìgbò naa.

Meji ninu awọn afurasi ọdaran ọhun la gbọ pe awọn Operation Burst ri mu ninu wọn. Àhámọ́ awọn Operation Burst ni wọn wà titi ta a fi parí akojọ iroyin yii.

Leave a Reply