Sanwo-Olu ati Igbakeji ẹ gbabẹrẹ ajẹsara Koro

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti gba abẹrẹ ajẹsara lati dena arun aṣekupani Koronafairọọsi.

Ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee yii, ni wọn fun Sanwo-Olu labẹrẹ ajẹsara ọhun nileewosan akanṣe fun itọju awọn arun to n ran ni, Infectious Disease Hospital (IDH) to wa ni Yaba, nipinlẹ Eko. Awọn aṣoju ajọ eleto ilera lagbAaye, WHO, atawọn lọgaa-lọgaa lẹnu iṣẹ ọba lọrọ naa ṣoju wọn nigba ti wọn fa egboogi Astra Zeneca COVID-19 naa si gomina lara, egboogi yii ni wọn lo maa tubọ gba itankalẹ arun Korona wọlẹ lawujọ wa.

Yatọ si Sanwo-Olu, Igbakeji rẹ, Dokita Ọbafẹmi Hamzat, naa gba abẹrẹ ajẹsara yii.

Ẹyin eyi lawọn kọmiṣanna kan atawọn darẹkitọ lawọn ẹka ileeṣẹ ọba naa gba abẹrẹ ajẹsara Korona tiwọn.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni kete to gba abẹrẹ naa tan, Gomina Sanwo-Olu sọ pe kawọn araalu ma kọbi-ara si ọrọ kan to n lọ nigboro pe oogun Korona yii le ni awọn akoba kan ninu, tabi pe oogun naa ko ṣee gbara le, Sanwo-Olu ni idi tawọn fi tẹwọ-gba abẹrẹ ajẹsara yii ni pe o maa mu adinku ba bi arun Korona ṣe fẹẹ gbilẹ nipinlẹ Eko.

Sanwo-Olu ni bi wọn ṣe gun oun labẹrẹ naa rọrun gan-an ni, oun o tiẹ mọ pe wọn fun oun ni nnkan kan rara, ko si ṣe oun bakan lẹyin toun gba a tan.

Gomina waa lo anfaani naa lati parọwa saraalu pe ki wọn ma ṣe dagunla si gbigba abẹrẹ ajẹsara naa, o ni o san ki wọn dena arun Korona ju ki wọn maa wa itọju lẹyin ti wọn ba ti lugbadi ẹ tan lọ.

Leave a Reply