Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọwọ ṣinkun ajọ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, tipinlẹ Kwara, ti tẹ baba ẹni ọdun marunlelọgọta kan, Samuel Darisa, ti wọn fẹsun kan pe o n ba ọmọ ọdun mẹwaa laṣepọ lagbegbe Agbadam, niluu Ilọrin.
Nigba ti wọn ṣafihan rẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni olu ileeṣẹ NSCDC, afurasi naa ni ki i ṣe pe oun fipa ba ọmọ naa sun o, o loun lo maa n gba foun lati ba a laṣepọ, ati pe ki i ṣe ẹẹkan tabi ẹẹmeji tawọn ti n ṣe e.
Ọga ajọ NSCDC nipinlẹ Kwara ni ọkan lara awọn ayalegbe ti wọn jọ n gbele lo ri wọn lasiko ti wọn n ba ara wọn sun, to si ta araadugbo lolobo ko too di pe wọn fi pampẹ ọba gbe afurasi naa.
Alukoro ileeṣẹ naa, Babawale Zaid Afọlabi, ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, o ni laipẹ lawọn yoo wọ ọ lọ sile-ẹjọ.