Ọga ileewe ni Alaaji Musibau, ọdun kẹta ree to ti n fipa ba aburo iyawo ẹ lo pọ n’Ilasamaja

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Eebu ati epe lawọn eeyan n fi ranṣẹ si afurasi ọdaran kan, Alaaji Musibau Salaam, oludasilẹ ati ọga agba ileewe Salaam Montessori, Primary and College ni Ilasamaja, latari bi wọn ṣe ni baba agbalagba naa ki aburo iyawo ẹ mọlẹ, to si n fipa ba a laṣepọ, ọmọ ọhun o si ju ọmọ ọdun mẹtala pere lọ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn oṣiṣẹ ẹka to n gba awọn obi atọmọleewe nimọran (Guidance and Counselling Unit) ni State Universal Baisc Education Board, SUBEB, ni wọn n lọ lati ileewe kan si omi-in lati ba awọn ọmọleewe sọrọ, ọwọ wọn ni awo ọrọ naa ya si.

Wọn lọmọ ta a forukọ bo laṣiiri naa jẹwọ pe ọkọ aunti oun ti n fipa ba oun sun lati ọdun 2019, ati pe ọkunrin naa lo gba ibale oun. Wọn lo sọ pe inu ọfiisi rẹ ninu ọgba ileewe rẹ to wa ni Ojule keji, Opopona Fayẹmi, Ilasamaja, nipinlẹ Eko, ni baba naa ti kọkọ ba oun sun, ọpọ igba lo si maa n fipa ba oun laṣepọ lẹyin igba naa.

Ọmọ naa sọ pe aunti oun to jẹ iyawo baba naa ko mọ si ọrọ yii, tori baba naa ti kilọ foun pe oun ko gbọdọ sọ fẹnikan, ati pe oun maa ran oun lọ siluu oyinbo laipẹ.

Awọn oṣiṣẹ SUBEB yii ni wọn fi ọrọ naa to ọlọpaa leti, ti wọn fi waa fi pampẹ ọba gbe Alaaji Musibau.

Wọn ni mọlẹbi iyawo Alaaji kan to sun mọ wọn daadaa sọ pe iyawo baba naa o le sọ p’oun o mọ nipa iṣẹlẹ yii, tori oun ti figba kan ta a lolobo lati ṣakiyesi kurukẹrẹ ọkọ ẹ lọdọ ọmọ ẹgbọn ẹ, ṣugbọn boya obinrin naa ko fẹẹ taṣiiri ọkọ ẹ tabi ẹru n ba a ni ko jẹ ko ṣe nnkan kan sọrọ naa nigba yẹn.

Ṣa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni Alaaji Musibau ti wa lọdọ awọn agbofinro, ni ẹka to n ri si iwa ọdaran abẹlẹ ati ọrọ awọn ọmọde, wọn si ti n ṣewadii to lọọrin nipa iṣẹlẹ ọhun.

Wọn ni ti iwadii ba ti pari, ọkunrin naa yoo foju bale-ẹjọ

Leave a Reply