Faith Adebọla, Eko
Iku oro, iku gbigbona, gbaa ni iku to mu ẹmi eeyan meji lọ lẹsẹkẹsẹ nibi ijamba ọkọ to waye loju ọna marosẹ Apapa si Oshodi nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii. Agbegbe Ilasamaja, lẹbaa biriiji Sadiku, nipinlẹ Eko, nijamba ọhun ti waye laarin bọọsi akero ti wọn n pe ni Faragọn kan ati tirela kan to gbe kọntena gbọọrọ sẹyin.
ALAROYE gbọ pe ki i ṣe pe awọn ọkọ naa dojukọ ara wọn, ọna ati maa bọ l’Oṣhodi lawọn mejeeji n tọ, ṣugbọn awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn royin pe bọọsi naa n duro lati ja ero, tawọn mi-in si n wọle lọwọ nibudokọ Ilasamaja naa ni, wọn ni idi rẹ wa nita diẹ, nigba ti tirela ti nọmba rẹ jẹ SGM 715 XA naa n ba ere buruku bọ ni tiẹ.
Wọn ni bi tirela naa ṣe pẹwọ lati gba ẹgbẹ bọọsi ọhun kọja ni irin kan kọ ibadi bọọsi ọhun, koloju si too ṣẹ ẹ, kọntena to gun niwọn ẹsẹ bata ọgun (20 feet) to ti n mi yẹgẹyẹgẹ lẹyin tirela ti idaamu ti ba naa re ja bọ lojiji, kongẹ ori bọọsi ọhun lo si ṣe. Koda, niṣe lo tẹ paanu bọọsi naa pẹlẹbẹ debii pe eeyan fẹrẹ ma mọ pe odidi bọọsi kan lo lẹ mọlẹ bẹẹ, o run un womu womu ni.
Ori ko awọn mẹfa kan yọ lọwọ iku ojiji, bo tilẹ jẹ pe wọn fara ṣeṣe pupọ, titi kan dẹrẹba bọọsi ọhun ti wọn lẹsẹ rẹ ti kan. Awọn to fara pa naa ti wa l’Ọsibitu Jẹnẹra Isọlọ, nibi ti wọn ti n fun wọn nitọju pajawiri.
Katapila lawọn ọṣiṣẹ ajọ LASEMA fi gbe kọntena tẹru kun inu rẹ fọfọ naa ki wọn too ri awọn oku ọhun yọ. Ọkunrin kan ati obinrin kan lawọn to kagbako iku ojiji naa, bo tilẹ jẹ pe ko ti i sẹni to da wọn mọ di ba a ṣe n sọ yii, ṣugbọn wọn ti gbe oku wọn lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba to wa n’Isọlọ ọhun.
Ọgbẹni Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ rọ awọn to ba mọ mọlẹbi awọn oloogbe naa lati fi iṣẹlẹ yii to wọn leti.
Ki Olorun Ki O ranwalowo Ni Orilede Yii