Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Aago mejila kọja iṣẹju diẹ lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni awọn ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre, eleyii ti Oloogbe Yinka Odumakin jẹ agbẹnusọ fun nigba aye rẹ, de sile awọn oloogbe lati ṣabẹwo ibanikẹdun sibẹ.
Igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ naa, Ọba Ọladipọ Ọlaitan lo ko awọn alagba ẹgbẹ latipinlẹ Ondo, Ọṣun, Ọyọ ati bẹẹ bẹẹ lọ sodi wa sibẹ.
Ninu ọrọ Ọba Ọladipọ Ọlaitan, o ni “Erin ti wo, ẹnu isa n ṣọfọ, ka too ri erin, o digbo, ka too ri ẹfọn o dọdan, ka too rẹni bii Yinka, o digbere. O sin wa, o sin gbogbo Yoruba, o ja ija naa de oju iku, a ko le gbagbe Yinka laelae.
“Iṣẹ ti Ọlọrun ran an lo waa jẹ o, ẹ jẹ ka maa dupẹ fun igbesi aye rẹ, ẹlomi-in lo ọgọrun-un ọdun ti ko ni i lorukọ, ti a ko ni i mọ ọn, ṣugbọn niwọn ṣoki ti Yinka gbe, o lo o fun gbogbo ilẹ Yoruba, o lo o fun idajọ ododo, ko bẹru ẹnikankan laye yii, o duro lori otitọ, o si sọ otitọ.
“A ṣi n wa bi a ṣe maa ri ẹni to le rọpo Yinka, ko ye wa, ṣugbọn Ọlọrun to fun wa yoo tu wa ninu, aa dẹ sọ bi a ṣe maa ṣe e, ṣugbọn lọwọ ti a wa yii, a ko mọbi ti a fẹẹ ya.
“Yinka jẹ ẹni to ṣe e fọkan tan, oun lo n jẹ Afẹnifẹre, Afẹnifẹre lo n jẹ Yinka, o fi gbogbo aye rẹ sin wa ni, ko si nnkan kan to yọ silẹ nibẹ, gbogbo ọjọ rẹ, tiwa ni. A ko mọ bi a ṣe maa ṣe o, ki ẹyin naa ba wa kun fun adura.
“Ọrọ itunu ti mo ni fun awọn obi to fi silẹ saye ni pe ki wọn maa yọ, wọn ko bimọ ti wọn yoo maa ru kaakiri nitori aisan. O ti ṣiṣẹ to waa ṣe laye, o si dagbere faye.”