Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Pẹlu bawọn eeyan kan ṣe n beere fun ipinya lorilẹ-ede yii, paapaa awọn igun Yoruba ti wọn n beere fun ilẹ Oduduwa, atawọn Ibo to n kede Biafra, ijọba apapọ ti kilọ fawọn eeyan naa lati dẹkun ẹ, bẹẹ lo ni kawọn ọmọ Naijiria ma tẹti si wọn rara.
Alaaji Lai Muhammed, Minisita fun eto iroyin ati aṣa, lo gba ẹnu ijọba apapọ sọrọ yii lọjọ Satide, niluu Eko. O ṣalaye pe ohun to wa nilẹ lasiko yii kọja ipinya tawọn eeyan yii n beere, ati pe ko si oore kan ti pinpinya naa yoo ṣe ẹnikẹni.
O fi kun un pe ki i ṣe tuntun mọ pe Naijiria niṣoro ẹlẹyamẹya, ti Boko Haram pẹlu iṣoro awọn Fulani ati agbẹ to n ṣẹlẹ kaakiri. O ni ṣugbọn ki i ṣe ipinya ni yoo ṣẹgun awọn iṣoro yii, ohun to yẹ ka ṣe ni pe ka wa ọna abayọ.
‘‘A mọ ohun to n ṣẹlẹ, gbogbo ẹ nijọba mọ, ti wọn si n ṣiṣẹ lori ẹ ko le baa daa. Ipinya kọ lo kan, nitori ori bibẹ kọ loogun ori fifọ. Ohun to so wa pọ ni Naijiria pọ ju ohun to pin wa niya lọ.’’ Bẹẹ ni Lai Muhammed wi.
Bakan naa lo ṣalaye pe ijọba mọ, pe bi ebi ba n pa ọmọ talaka, ọmọ olowo paapaa ko ni i foju ba oorun bi ọmọ tebi n pa ba bẹrẹ iwa ipanle fun un.
Ṣugbọn ki i ṣe pe ki ọlọmu waa da ọmu iya rẹ gbe lo kan, o ni kawọn eeyan to n beere fun ipinya yii yee sọ bẹẹ, kawọn to n tẹle wọn paapaa si pada lẹyin wọn.