Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Kẹmi Afọlabi Adeṣipẹ, ọkan lara awọn oṣerebinrin nilẹ yii, ti jẹ ko di mimọ pe ojojo n ṣogun, o ni ara ogun oun ko le. Ṣugbọn bi Kẹmi ṣe sọ pe ara oun ko ya to, bẹẹ naa lo ni ko si ifoya kankan.
Oju opo Instagraamu rẹ ni Kẹmi to ṣi ile rẹ laipẹ yii ti kede aiya ara naa.
Fọto kan to ya loko ere ninu oṣu kejila, ọdun to kọja, ni obinrin naa ju sori afẹfẹ, ohun to si kọ sẹgbẹẹ fọto naa ree:
‘’Eyi ni iṣẹ ti mo ṣe kẹyin ninu oṣu kejila, ọdun 2020. Mi o ti i ni anfaani lati lọ soko ere kankan fun iṣẹ ni 2021 yii, nitori aiyaara. Mo dupẹ f’Ọlọrun pe mo ṣi n mi. Mi o ṣaroye o, mo kan n fi ẹmi imoore han s’Ọlọrun ni.
‘‘Si gbogbo ẹni to n dojukọ iṣoro kan lọwọ, Ọlọrun yoo mu yin la a ja. Mo ni ohun ti mo maa ba eyin ololufẹ Kẹmi Afọlabi sọ. Lonii kọ sa, laipẹ lọjọ mi-in ni.’’
Awọn eeyan to ri ohun to kọ naa bẹrẹ si i ṣadura fun un loju opo yii ni, wọn ni alaafia yoo to o laipẹ, Ọlọrun yoo mu Kẹmi Afọlabi pada sipo ilera to peye.
Ẹ oo ranti pe igba kan lọdun 2021 yii, ninu oṣu keji, ni Kẹmi gbe ọrọ kan jade nipa bo ṣe rẹ ẹ to lẹyin to ṣe ayẹyẹ kan.
Oṣere yii sọ pe oun naa mọ pe oun ko gbo, o ni agiriiki loun. O ni niṣe ni dokita ati nọọsi fi oogun oorun sinu omi ti wọn n fa soun lara, koun le sun, koun si fun ara nisinmi daadaa.
Igba kan naa wa to rẹ oṣere yii ni Mẹka, nigba to lọọ ṣiṣẹ Hajji ni Saudi lọdun 2019. Ṣugbọn alaafia pada to o.