Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn meji ni wọn pade iku ojiji lọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, pẹlu bi ọlọkada kan ṣe ṣeesi ko sabẹ ọkọ akoyọyọ kan nibi to bajẹ si lagbegbe High Court, niluu Akurẹ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọlọkada ọhun nikan ni wọn lo kọkọ ku loju-ẹsẹ tiṣẹlẹ yii waye nigba ti ero to gbe ku si ileewosan tawọn alaaanu kan sare gbe e lọ lẹyin ti ijamba naa waye.
Diẹ lo ku ki rogbodiyan bẹ silẹ latari iṣẹlẹ ọhun pẹlu bawọn janduku kan ṣe binu dana sun ọkọ akoyọyọ naa mọ ibi to bajẹ si.
Eyi lo ṣokunfa bawọn ọmọ ẹgbẹ awakọ akoyọyọ ẹka tilu Akurẹ naa ṣe sare ko ara wọn jọ lati fẹhonu han ta ko bi wọn ṣe dana sun ọkọ naa.
Oludamọran fun gomina lori ọrọ aabo, Ọgbẹni Jimoh Dojumọ to tete ko awọn ẹsọ alaabo kan sodi lọ síbi iṣẹlẹ naa lo pana wahala ti i ba suyọ lọjọ ta a n sọrọ rẹ yii.
Ninu ọrọ Dojumọ lasiko to n pẹtu sọkan awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ọhun, o rọ wọn lati mu suuru fun ijọba nitori pe o dandan ki awọn ṣawari gbogbo awọn to lọwọ si bi wọn ṣe sun ọkọ tipa naa nina, ki wọn si waa foju wina ofin.