Amotẹkun ti mu awọn Fulani to fipa ba awọn obinrin ti wọn ji gbe lo pọ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ajinigbe mẹrin kan lọwọ ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo tẹ niluu Akurẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.

ALAROYE gbo pe Alakooso wọn nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, lawọn ti n tọpasẹ awọn ajinigbe ọhun lẹyin ti wọn ji awọn eeyan kan gbe lagbegbe Pepele, nitosi Ọda, nijọba ibilẹ Gusu Akurẹ.

O ni ojo nla to rọ lọjọ naa lawọn oniṣẹẹbi naa fi boju ti wọn fi raaye ji awọn eeyan ọhun gbe.

Oloye Adelẹyẹ ni awọn fidi rẹ mulẹ ninu iwadii awọn pe awọn janduku ọhun ti fipa ba diẹ ninu awọn ti wọn ji gbe naa lo pọ ki awọn oṣiṣẹ Amọtẹkun too ri wọn gba pada.

O ni gbogbo awọn ti wọn ji gbe lawọn ti ri gba pada ati pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply