Faith Adebọla
Awa agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC ba Aare orilẹ-ede yii, Muhammadu Buhari, ileeṣẹ ologun, ati mọlẹbi awọn ṣọja ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ofurufu to waye lọjọ Eti, Furaidee, to kọja yii, nipinlẹ Kaduna, kẹdun gidigidi. A gbadura ki Ọlọrun tu wọn ninu.
A o fara mọ bawọn kan ṣe n pariwo lọtun-un losi pe awọn fẹ ki Naijiria pin, atawọn ti wọn n sọ awọn ọrọ to le ko ba alaafia ilu. A gba awọn eeyan ti wọn n gbe ero yii kiri niyanju pe ki wọn jawọ ninu ẹ. Ohun ti awa duro fun ni isọkan Naijiria ati ilọsiwaju rẹ.
Awa naa mọ daadaa pe eto aabo mẹhẹ lorile-ede yii, paapaa lori bi awọn afẹmiṣofo ṣe n kọ lu awọn eeyan kiri, ti awọn ajinigbe atawọn iwa ọdaran mi-in ti gbilẹ kaakiri awọn agbegbe kọọkan lorilẹ-ede yii, eyi to n ko ba alaafia araalu.
A wa n rọ ijọba apapọ lati tubo ṣiṣẹ lori eto aabo, ki wọn ro awọn ẹṣọ alaabo lagbara, ki awọn eeyan le fẹdọ lori oronro.
O jẹ ohun to baayan ninu jẹ pe awọn eeyan pataki pataki laarin ilu wa lara awọn to n sọ awọn ọrọ to le da eto alaafia ilu ru, a wa n fi asiko yii rọ ijọba ni gbogbo ipele iṣakoso atawọn ẹṣọ eleto aabo lati sa gbogbo ipa wọn lori bi alaafia yoo ṣe pada saarin ilu, ki iṣọkan le fẹsẹ rinlẹ daadaa.
Bakan naa la fẹ kijọba tubọ ṣeto aabo sawọn ibi tawon janduku afẹmiṣofo ti kọ lu ri, ati sawọn ibomi-in kaakiri orilẹ-ede yii.
Eto ijọba ti agbara yoo wa fun awọn ipinlẹ lati lo ohun alumọọni wọn fun idagbasoke ilu lawa naa nigbagbọ ninu ẹ. Ijọba ti agbara yoo wa fun awọn ipinlẹ lati ṣiṣẹ idagbasoke wọn, ti agbara ijọba apapọ yoo dinku loke. Iru eto ijọba yii yoo fun awọn ijọba ipinlẹ lanfaani lati ni ọlọpaa ipinlẹ.
Bakan naa la fọwọ si ipade ati ipinnu tawọn gomina iha Guusu ṣe niluu Asaba, nipinlẹ Delta laipẹ yii lori ipese ibi-ijẹko fawọn maaluu. A gbagbọ pe igbesẹ wọn yii yoo mu opin de ba wahala to n ṣẹlẹ laarin awọn agbẹ atawọn darandaran, ti yoo si mu eto ọrọ-aje wọn ru gọgọ si i.