Awọn agbaagba ẹgbẹ APC nilẹ Yoruba lawọn o fẹ ‘Orileede Oodua’

 Faith Adebọla, Eko

Awọn agbagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti kede pe awọn o fara mọ bawọn kan ṣe n fọnrere pe awọn maa ya kuro lara orileede Naijiria yii, wọn lawọn koro oju si iru igbesẹ bẹẹ ni tawọn.

Nibi ipade pataki kan to waye nile ijọba Eko to wa lagbegbe Marina, l’Erekuṣu Eko, lọjọ Aiku, Sannde yii, ni wọn ti sọrọ ọhun nigba ti wọn n jabọ ipade wọn.

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Oloye Bisi Akande, lo ka ipinnu awọn agbaagba ọhun jade fawọn oniroyin, lẹyin bii wakati mẹta aabọ ti wọn ti tilẹkun mọri, o ni dipo ki orileede yii pin, niṣe ni kijọba apapọ ṣe gbogbo ohun to ba wa lagbara wọn lati jẹ ki Naijiria wa niṣọkan, ki eto aabo to mẹhẹ yii si rodo lọọ mumi.

Bakan naa ni wọn lawọn fara mọ ipinnu tawọn gomina Guusu ilẹ wa ṣe nipa fifofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba lawọn agbegbe wọn, ṣugbọn wọn parọwa sijọba apapọ lati ṣeto owo iranwọ lati banki apapọ ilẹ wa, eyi tawọn ijọba ipinlẹ, ibilẹ atawọn ẹni kọọkan le ri lo lati kọ awọn ibudo ijẹko tigbalode fawọn darandaran.

Lara awọn agbaagba to pesẹ sipade naa ni gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ ri, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ ri, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Oloye Bisi Akande, Gomina Gboyega Oyetọla tipinlẹ Ọṣun, Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko, Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun, Olori awọn aṣoju-sofin l’Abuja, Fẹmi Gbajabiamila atawọn meji mi-in.

Bakan naa lawọn agbaagba yii lawọn fẹ kijọba apapọ ṣeto fun idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ, ki eto aabo le tubọ lagbara si i, ki wọn si faaye gba atunto si ofin ilẹ wa ati ọna iṣakoso Naijiria.

Leave a Reply