Wọn tun ji eeyan mẹta mi-in gbe l’Abẹokuta, akẹkọọ FUNNAB wa ninu wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Iṣẹlẹ obinrin ti wọn ji gbe nileewe TASUED, n’Ijẹbu-Ode, l’Ọjọbọ to kọja lawọn eeyan ṣi n sọ lọwọ ti awọn ajinigbe tun fi ṣọṣẹ mi-in lọjọ Satide to kọja yii, eeyan mẹta mi-in ni wọn tun ji gbe l’Abẹokuta, ọkunrin meji, obinrin kan. Akẹkọọ ileewe ọgbin, FUNNAB, Toyinbo Nathaniel Ọlayinka, wa lara awọn ti wọn ji gbe naa.

Irọlẹ ọjọ Satide ọhun ni iroyin jade pe Toyinbo, akẹkọọ to wa nipele kẹrin nileewe imọ ogbin, FUNNAB, l’Abẹokuta, bọ sọwọ awọn agbebọn kan ti wọn ya bo wọn lojiji, iyẹn ninu oko ọkunrin kan ti wọn n pe ni Dominic.

Awọn agbebọn yii gbe Dominic pẹlu, bẹẹ ni wọn gbe ọmọbinrin kan tọjọ ori ẹ ko ju mẹtadinlogun lọ. Ọmọ orile-ede Togo lọmọbinrin naa.

Abule Itoko, l’Ọdẹda, lọna to lọ s’Ibadan lati Abẹokuta, loko naa wa.

Alukoro ileewe FUNNAB, Kọla Adepọju, ṣalaye pe akẹkoọ ti wọn ji gbe loko yii ti n gbe inu oko naa lati ọdun kẹta sẹyin. O ni o n kẹkọọ si i nibẹ nipa ohun to n kọ nileewe ni, bẹẹ lo n fi ṣenji diẹdiẹ to n ri nibi iṣẹ to n ṣe naa ṣe anfaani funra rẹ.

Afi bawọn ajinigbe ṣe wa sibẹ, ti wọn si gbe oun atọga rẹ pẹlu ọmọ Togo naa lọ ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ ojọ naa.

Titi ta a fi pari iroyin yii, wọn ko ti i gburoo ohunkohun latọdọ awọn ajinigbe naa. Koda, ko ti i sẹni to gbọ nnkan kan nipa obinrin ti wọn gbe lọ ni TASUED l’Ọjọbọ to kọja yii naa, iyẹn Abilekọ I.B Abimbọla.

Ijẹbu-Ode ni wọn ti ji obinrin to jẹ Igbakeji adari lẹka imọ ẹrọ ileewe naa gbe, ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ naa.

Lati oṣu bii mẹta sẹyin ni ijinigbe ti di nnkan gbogbo igba nipinlẹ Ogun, awọn ajinigbe n ṣọṣẹ ni Yewa, Abẹokuta ati Ijẹbu, wọn ko si mọ ẹnikan leeyan ki i gbe, ẹni ti wọn ba ri naa ni wọn n gbe wọgbo lọ.

Ni ti eyi to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ yii, awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun lawọn ti bẹrẹ iṣẹ lori ẹ, wọn lawọn yoo ridii ọrọ naa laipẹ.

 

Leave a Reply