Florence Babaṣọla
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe oun to lewu pupọ ni bi awọn eeyan kan ko ṣe ni ibomi-in lati doju ija kọ bayii ju agọ ọlọpaa lọ.
O ni ko le si aabo to peye fun awọn araalu nibikibi ti wọn ba ti n doju ija kọ awọn agbofinro, ti wọn ko si faaye gba wọn lati ṣiṣẹ lai si ibẹru.
Laafin rẹ lo ti sọrọ yii lasiko to n gbalejo Igbakeji ọga agba ọlọpaa to wa fun ẹka kọkanla, AIG Ọlaṣupọ Ajani. Kabiesi sọ pe iwa yii le fa ọwọ aago eto ọrọ-aje sẹyin.
Oluwoo ṣalaye pe bii igba ti wahala jokoo jẹẹjẹ, ti awọn kan n fa a lẹsẹ ni ki wọn maa dunkooko tabi halẹ mọ awọn agbofinro ti wọn n daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu.
Ọba Akanbi ṣapejuwe iwa naa gẹgẹ bii eyi to yẹ ki gbogbo eeyan koro oju si nitori o le da ogun silẹ.
O ni ijọloju lo jẹ pe awọn agbofinro ko le fọwọ sọya tabi yan fanda laarin igboro mọ, koda, ọpọ ninu wọn ni ko le wọ aṣọ iṣẹ rẹ laarin ilu, asiko ti to bayii lati ṣatunṣe aṣa buburu naa, ki ijọba si tete da si i ko too lagbara ju bayii lọ.
O ke sijọba lati tubọ gba awọn ọdọ si iṣẹ agbofinro lorileede yii, ki wọn si ṣatunṣe owo ti ko to nnkan ti awọn ti wọn n ṣiṣẹ naa bayii n gba.