Taofeek Sudiq, Ado Ekiti
Bi eeyan ba jẹ ori ahun, poroporo ni omije yoo maa jade loju rẹ bi tọhun ba wa nibi isinku ọlọpaa kan, Inspẹkitọ Adewumi Abiọla, to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti tawọn ajinigbe kan ti wọn ko ti i mọ yinbọn pa.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹfa, ọdun yii, ni awọn agbebọn naa sadeede ya wọ ileeṣẹ awọn oyinbo kan ni agbegbe Ọdẹda, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, lẹyin ti wọn le mẹrin lara awọn oyinbo wọnyi lati ilu Ibadan wa si agbegbe naa.
Awọn agbebọn naa ti wọn ko din ni mẹjọ ni wọn dana ibọn bolẹ, nibi ti ọlọpaa yii si ti n gbero lati doola ẹmi awọn oyinbo to n ṣọ yii lo ti fara gbọta ibọn to si ku loju-ẹsẹ.
Awọn agbebọn naa ni wọn ji meji lara awọn oyinbo to gba iṣẹ ọna Reluwee yii gbe, ti ẹnikẹ́ni ko si ti i mọ ibi ti wọn gbe wọn lọ.
Oloogbe yii jẹ ẹṣọ pataki lati olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ to n ṣọ lara awọn oyinbo yii.
Oku ọkunrin yii ni awọn ọlọpaa ẹgbẹ rẹ gbe wa si ilu ti wọn ti bi i ni Igbimọ-Ekiti, nijọba ibilẹ Ido/Osi, lati ilu Ibadan, ti wọn si sin oku rẹ si ilẹ rẹ to n kọ lọwọ ni ilu naa.
Oloogbe yii ni iya arugbo to jẹ ẹni ọgọrin ọdun, ti orukọ rẹ n jẹ Olubiyo Abiọla ati iyawo rẹ to jẹ ẹni mejidinlogoji pẹlu ọmọ mẹrin ti wọn wa nileewe alakọọbẹrẹ.
Meji lara awọn ẹgbọn oloogbe yii, Caroline Bamigboye ati Taiwo Ogunrinde, ti wọn tẹle oku naa de iboji sọ pe o to ogun ọta ibọn to wọ inu ara oloogbe naa nigba ti awọn ajinigbe naa yinbọn si i.
Ninu ọrọ tirẹ, Alaga ẹgbẹ ajọ akọroyin nipinlẹ Ekiti, Oloye Laolu Ọmọsilade, to jẹ ẹgbọn fun oloogbe naa gboṣuba fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fun iṣẹ ribiribi ti wọn ṣe lati jẹ ki wọn tete ri oku oloogbe naa gba jade.
Ọmọsilade pe awọn oyinbo to n ṣe iṣẹ ọna Raluwee ti ọlọpaa yii n ṣọ to fi ku ki wọn dide iranlọwọ fun awọn mọlẹbi ati iya arugbo ti oloogbe yii fi silẹ lọ.
“Abíọ́lá nikan ni ọmọkunrin to ku fun iya arugbo yii ko too di pe o ba iku ojiji pade. O fi kun un pe ki wọn jọwọ, ki wọn ran idile yii lọwọ, ni pataki ju lọ, awọn ọmọ oloogbe yii.”