Ole mẹta ja mọto gba l’Ondo, wọn lasidẹnti l’Ogun, lẹnikan ba ku ninu wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Mẹta lawọn ọkunrin tẹ ẹ n wo fọto wọn yii ko ba jẹ, ẹni kẹta ti wọn jọ ja mọto gba nipinlẹ Ondo ku ni, iyẹn lẹyin ti wọn fi mọto ọhun lasidẹnti l’Ode-Rẹmọ, ipinlẹ Ogun.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹfa yii, lawọn ole mẹta naa ja mọto Toyota Camry kan gba loju ibọn, nipinlẹ Ondo. Bi wọn ti gba a tan ni wọn kọri si ipinlẹ Eko. Ṣugbọn wọn ko ti i de Eko ti wahala fi de ba wọn.

Ode-Rẹmọ, nipinlẹ Ogun, ni wọn de ti wọn fi kagbako ijamba ọkọ.  Niṣe ni mọto ti wọn ja gba naa fori sọ pepele kan loju ọna, nitori iwakuwa tawọn ole naa n wa lagbara pupọ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe wi.

Bi mọto naa ṣe fori sọ pepele ọhun lo gbokiti, awọn mẹtẹẹta ti wọn si wa ninu ẹ fara ṣeṣe gidi.

Awọn ọlọpaa Ode-Rẹmọ to wa nitosi lo sare gbe wọn lọ sọsibitu, tawọn dokita si bẹrẹ si i tọju wọn.

Ọsibitu ọhun ni wọn wa ti olobo ti ta DPO teṣan Ode-Rẹmọ, CSP Faṣọgbọn Ọlayẹmi, pe adigunjale lawọn eeyan mẹta ti wọn gbe lọ sọsibitu, ati pe wọn ja mọto Camry ti wọn gbe de ilu naa gba loju ibọn ni.

Ẹni to ni ọkọ Camry naa funra ẹ wa lati Ondo, o ṣalaye fawọn ọlọpaa Ogun pe awọn ọkunrin marun-un lo da oun lọna, aṣọ ọlọpaa ni wọn wọ, niṣe ni wọn si wọ oun bọ silẹ ninu mọto naa, ti wọn yọ ibọn soun, bẹẹ ni wọn si ṣe gbe mọto naa lọ.

Bi DPO Ode-Rẹmọ ṣe gbọ eyi lo paṣẹ pe ki wọn mu awọn ọkunrin naa bii ole, ṣugbọn nibi ti wọn ti n gbatọju lọwọ naa ni ọkan ninu wọn ti wọn pe orukọ ẹ ni Emeka John ti ku, awọn meji to ṣẹku bayii ni Sunday Emmanuel ati Idris Ibrahim.

Ọga ọlọpaa Ogun, CP Edward Ajogun, ti paṣẹ pe ki wọn da awọn meji yii pada s’Ondo, nibi ti wọn ti daran, ibẹ naa ni wọn yoo ti gbe wọn lọ sile-ẹjọ.

 

Leave a Reply