Ọlawale Ajao, Ibadan
Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, ti sọ pe bi igbin ba fa, ikarahun a tẹle e, lọrọ oun ati adari ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, bo ṣe n gbero lati dije dupo aarẹ orile-ede yii lọdun 2023.
Ninu atẹjade kan to tọwọ alakooso-agba ikọ olupolongo fun Tinubu jade lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2021, yii ti i ṣe
ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, l’Ọba Adetunji ti fọwọ sọya bẹẹ lasiko to gbalejo ikọ alatilẹyin Tinubu laafin rẹ to wa ni Popo Yemọja, n’Ibadan.
Abẹwo ọhun ni ikọ to n polongo ibo aarẹ fun Aṣiwaju Tinubu ṣe lati gba iwure agba lẹnu Olubadan lati jẹ ki ipo aarẹ tẹ agba oselu naa lọwọ lasiko idibo odun to n bọ ọhun.
Ọba Adetunji, ẹni to gba awọn ikọ naa tọwọ-tẹsẹ, ṣapejuwe Tinubu gẹgẹ bii ẹni to kunju oṣunwọn lati ṣamulo erongba ẹgbẹ iṣejọba oṣelu APC lati mu ayipada rere ati itẹsiwaju ba orile-ede Naijiria, paapaa, lẹka eto ohun igbayegbadun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Eeyan atata ni Tinubu, gbogbo agbara mi ni ma a si ṣa lati ti i lẹyin lori erongba rẹ lati dije dupo aarẹ lọdun 2023.
Lasiko ti wọn ṣabewo s’ori ade naa lati fiṣe Tinubu jẹ, ki wọn si gba iwure latẹnu Olubadan ni Adari ikọ ipolongo naa, Dokita Johnny Benjamin, fidi ẹ mulẹ pe tọsan-toru lawọn ikọ yii n ṣiṣẹ lati mu ki Tinubu ṣaṣeyọri dori ipo aarẹ nitori oun lẹni naa to le mu iṣọkan ba orileede yii.