Faith Adebọla
Latari lẹta ti wọn ni Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba AbdulRosheed Akanbi, kọ si Aarẹ wa, Muhammadu Buhari, pe oun ti ba gbajugbaja ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, sọrọ, o si ti gba lati jawọ ninu akitiyan rẹ fun idasilẹ orileede Oodua, Sunday Igboho ti sọrọ, o ni ko sohun to le da oun duro bẹẹ, loun o ni i jawọ erongba oun ọhun.
Sunday Igboho sọrọ yii latẹnu agbẹnusọ rẹ, Ọlayọmi Koiki, lọjọ Abamẹta, Satide yii, Koiki ni ko si ọrọ ajọsọ kan to jọ eyi ti wọn lo wa ninu lẹta Oluwoo ọhun pẹlu ọga oun, bẹẹ ni iṣẹlẹ to ṣẹlẹ si Sunday Igboho ko le mu ko jawọ bibeere fun ‘Yoruba Nation’ rara.
“Titi di bi mo ṣe n sọrọ yii, ko si ajọsọ kan to jọ bẹẹ laarin Oloye Sunday Igboho pẹlu Ọba Akanbi tabi ẹnikẹni, koda ko si ipe ori aago kan paapaa.
“Fọto kan ti wọn n gbe kiri ori ẹrọ ayelujara nibi ti Igboho ti dọbalẹ fun Oluwoo, fọtọ atijọ ni, ọdun 2018 ti Ọba naa ṣẹṣẹ gori itẹ ni wọn ti ya a, nigba ti Igboho lọọ ki i.
Gbogbo ẹni to ba n sọ pe boya Sunday Igboho ti lọọ sinmi tabi pe o ti jawọ ninu igbesẹ rẹ, irọ gbuu ni, ipinnu rẹ ko yi pada dọla.
Ko si ohun to le bomi sọkan Sunday Igboho, bẹẹ ni ko si ẹni to le sọ pe ko jawọ rara.