Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, eyi ti i ṣe aago kan ọsan kọja iṣẹju mẹẹẹdogun l’Ọjọbọ, ọjọ karun-un, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 yii, ko din ni marundinlogoji (35) ninu awọn agunbanirọ to wa ninu ọgba wọn ni Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, to ti lugbadi arun Korona, gẹgẹ bi Kọmiṣanna eto ilera nipinlẹ naa, Dokita Tomi Coker, ṣe fidi ẹ mulẹ.
Opin ọsẹ to kọja yii ni wọn ṣi awọn agọ agunbanirọ kaakiri orilẹ-ede yii, awọn iṣi keji (Batch B, Stream 1) to fẹẹ sinru ilu, eyi ti ko yọ ipinlẹ Ogun silẹ.
Nigba to n ṣalaye nipa Korona to tun bẹrẹ si i pọ si i yii, Dokita Coker sọ pe awọn ti ko awọn to lugbadi Korona naa lọ sibudo iyasọtọ, nigba ti awọn mi-in n gba itọju nile.
O fi kun un pe lati ibẹrẹ oṣu kẹjọ yii ni aisan naa ti n pọ si i nipinlẹ Ogun. O ni ninu oṣu kẹfa, ko to nnkan rara, eeyan to si wa nibudo iyasọtọ ko ju meji lọ.
Nigba to di oṣu keje to pari yii, aisan naa tun pọ si i gẹgẹ bi kọmiṣanna ṣe wi. Nigba ti oṣu kẹjọ si bẹrẹ, niṣe lo di pe eeyan bii meje lojumọ, nigba mi-in eeyan mẹrindinlogun lo maa n lugbadi ẹ lojumọ kan.
Ibudo iyasọto to wa lọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ, ni Ṣagamu, eyi to jẹ eeyan meji lo wa nibẹ ninu oṣu kẹfa, ti gbalejo eeyan mejila mi-in bayii, eeyan marundinlogoji (35) lo si wa ni t’Ikẹnnẹ, nigba ti awọn mọkanlelaaadọrin (71) mi-in ti ni Korona, ti wọn n gba itọju tiwọn nile.
Lori ohun to fa a ti Korona tun fi gbera sọ bayii, Dokita Coker sọ pe awọn eeyan ti ko gba abẹrẹ ajẹsara Korona lo lugbadi ẹ yii.
O ni o ṣe ni laaanu pe bi ipolongo ṣe waye to pe kawọn eeyan lọọ gba abẹrẹ yii, awọn eeyan kan dagunla si i.
O rọ awọn ti wọn ko ba ti i gba abẹrẹ naa ti wọn si ti pe ẹni ọdun mejidinlogun lati ṣe bẹẹ, nitori anfaani rẹ mi-in tun ti ṣi silẹ bayii nijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ Ogun.
Yatọ si eyi, fifọ ọwọ deede, lilo ibomu ati yiyago funra ẹni lawọn ibi tero ba pọ si naa ṣi wa ninu ofin tawọn eeyan gbọdọ maa tẹle, lati le dena Korona ẹlẹkẹẹta ti wọn tun n kede ẹ yii, gẹgẹ bijọba ṣe wi.