Nitori ẹsun ipaniyan, adajọ sọ baba arugbo sẹwọn ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ Majisreeti kan to wa niluu Ilọrin ti paṣẹ pe ki baba ẹni ọgọta ọdun le marun-un kan, Abdulsalam Saheed Akanbi, lọọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn Mandala, to wa ni Ilọrin, ipinlẹ Kwara, fẹsun pe o ṣeku pa ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Sanni Abubakar, niluu Bode-Saadu, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni Zacchaeus Folorunsho wọ Akanbi lọ siwaju Majisreeti Abdulraheem Bello, fẹsun pe o lọwọ ninu iku ọmọ oun ti wọn ba oku rẹ ninu igbo, tori pe wọn ri ibi ti baba naa ti da erupẹ bo ẹjẹ ọmọ ọhun mọlẹ ninu oko rẹ. O rọ ile-ẹjọ ko ma ṣe gba beeli baba naa.

Majistreeti Bello ko fakoko ṣofo to fi ni ki wọn maa gbe ọmọkunrin naa lọ si ọgba ẹwọn Mandala titi ti igbẹjọ mi-in yoo fi waye ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 yii.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Oṣere tiata yii pariwo: Ẹ gba mi o, latọjọ ti mo ti ṣojọọbi mi ni itẹkuu lawọn oku ti n yọ mi lẹnu

Monisọla Saka Kayeefi! Inu iboji larakunrin yii ti ṣe ọjọ ibi ẹ. Oṣerekunrin ilẹ Ghana …

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: