Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun bẹ ori akẹkọọ Kwara Poli, n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun sẹku pa gende kan torukọ rẹ n jẹ Ọlawale niluu Ilọrin nipinlẹ Kwara, lẹyin ti wọn dena de e lọna ile rẹ, ni iya ọmọ naa ba bu sẹkun nigba to gbọ iku ọmọ rẹ.

Ni owurọ kutukutu, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni wọn ba ori Ọlawale nikorita Unity, niluu Ilọrin, lẹyin ọpọlọpọ wakati ti iya ọmọ naa ti n wa a, ti ko si mọ ibi ti ọmọ rẹ wa. Bakan naa ni wọn o ti i mọ ẹni to ni ori naa, ṣugbọn nigba ti iroyin kan iya naa pe ori kan wa ni agbegbe Unity, lo lọ si agọ ọlọpaa, to si ri i pe ọmọ oun, Ọlawale, ni wọn ge ori rẹ ẹ.

Ọlawale ni wọn ni o tun jẹ ọkan lara awọn to n tun foonu ṣe ni ọja to wa lagbegbe Challenge. Gẹgẹ bii iya rẹ ṣe ṣalaye, o ni ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni Ọlawale jade nile, ti ko si dari pada wale ni akoko to yẹ ko wọle. Obinrin naa ni oun pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ, ko gbe e, o ni awọn ti bẹrẹ si i kọminu lori ọmọ ọhun, afi bi oun ṣe de ikorita Unity, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti oun ri awọn eeyan to pe jọ, ori Ọlawale, ọmọ oun, ni wọn n pe wo.

Alukoro Ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, sọ pe iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, tawọn yoo si fi awọn amookun ṣeka naa jofin. Ọkasanmi tẹsiwaju pe iwadii ti wọn ti ṣe siwaju fi han pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni awọn to pa Ọlawale, ati pe ọmọkunrin naa jẹ ọkan lara ẹgbẹ naa nileewe Kwara Poli.

 

Leave a Reply