Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, sọ ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan, ti wọn forukọ bo laṣiiri sẹwọn fẹsun pe o dana sun akẹgbẹ rẹ, Fatimon Jako.
ALAROYE, gbọ pe ede-aiyede kekere kan lo bẹ silẹ laarin ọmọ ikọsẹ imọ oogun oyinbo kan to n kọṣẹ ni ṣọọbu ọkunrin kan to n jẹ Joseph Friday n’Ilọrin, ati akẹgbẹ rẹ, Fatmon Jako, ti ọmọbinrin ọhun si wọ inu yara oloogbe lọ, o ba a to sun, o tu epo bẹntiroolu le e lori, lo ba dana sun un laaye.
Wọn sare gbe Fatimon lọ si ileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin fun itọju, ṣugbọn ọsibitu yii lo ku si latari pe ina ti jo o kọja aala. Olujẹjọ jẹwọ pe loootọ loun dana sun un, tori ede-aiyede to wa laarin awọn mejeeji loun ṣe ṣe bẹẹ.
Agbefọba, Inspẹkitọ Sekunda Olayide, waa rọ ile- ẹjọ pe ko fi ọmọdebinrin ọhun si ahamọ tori iwa ọdaran lo hu, ki i ṣe ẹni ti wọn le gba beeli rẹ.
Magistreeti F. O. Olokoyo, paṣẹ pe ki wọn fi ọmọbinrin ọhun si ọgba ẹwọn, o si sun igbẹjọ miiran si ọgbọn ọjọ, oṣu kẹjọ, ọdun yii, titi ti imọran yoo fi wa lati ileeṣẹ ẹka eto idajọ lori ibi ti ọrọ rẹ yoo ja si.