Nitori to dana sun akẹgbẹ ẹ, adajọ sọ ọmọ ọdun mẹrindinlogun sẹwọn n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, sọ ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan, ti wọn forukọ bo laṣiiri sẹwọn fẹsun pe o dana sun akẹgbẹ rẹ, Fatimon Jako.

ALAROYE, gbọ pe ede-aiyede kekere kan lo bẹ silẹ laarin ọmọ ikọsẹ imọ oogun oyinbo kan to n kọṣẹ ni ṣọọbu ọkunrin kan to n jẹ Joseph Friday n’Ilọrin, ati akẹgbẹ rẹ, Fatmon Jako, ti ọmọbinrin ọhun si wọ inu yara oloogbe lọ, o ba a to sun, o tu epo bẹntiroolu le e lori, lo ba dana sun un laaye.

Wọn sare gbe Fatimon lọ si ileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin fun itọju, ṣugbọn ọsibitu yii lo ku si latari pe ina ti jo o kọja aala. Olujẹjọ jẹwọ pe loootọ loun dana sun un, tori ede-aiyede to wa laarin awọn mejeeji loun ṣe ṣe bẹẹ.

Agbefọba, Inspẹkitọ Sekunda Olayide, waa rọ ile- ẹjọ pe ko fi ọmọdebinrin ọhun si ahamọ tori iwa ọdaran lo hu, ki i ṣe ẹni ti wọn le gba beeli rẹ.

Magistreeti F. O. Olokoyo, paṣẹ pe ki wọn fi ọmọbinrin ọhun si ọgba ẹwọn, o si sun igbẹjọ miiran si ọgbọn ọjọ, oṣu kẹjọ, ọdun yii, titi ti imọran yoo fi wa lati ileeṣẹ ẹka eto idajọ lori ibi ti ọrọ rẹ yoo ja si.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: