Faith Adebọla
Meji lara awọn minisita to n ba ijọba apapọ ṣiṣẹ, Minisita lori feto ọgbin, Alaaji Mohammed Sabo Nanono, ati Minisita lori ọrọ agbara, Alaaji Mamman Saleh, ti padanu ipo wọn, Aarẹ Muhammadu Buhari ti gbaṣẹ lọwọ wọn, o si ti yan awọn meji mi-in rọpo wọn lẹsẹkẹsẹ.
Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin ati ipolongo, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣinam, lo kede ọrọ yii lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, l’Abuja, ninu atẹjade kan.
Fẹmi Adeṣina tun kede pe Aarẹ Buhari ti yan Minisita lori ọrọ ayika tẹlẹ, Mohammed Mahmoud Abubakar, lati di minisita feto ọgbin, bakan naa ni wọn gbe minisita agba ni ileeṣẹ ode ati ile gbigbe, Abubakar Aliyu, lọ si ileeṣẹ agbara gẹgẹ bii minisita bayii.
Atẹjade naa ko sọ idi pato ti Aarẹ fi ṣe ipinnu yii.
Adeṣina ni Buhari dupẹ lọwọ awọn mejeeji, o si ṣadura ki wọn ṣoriire ninu ohun yoowu ti wọn ba dawọ le bi wọn ṣe n pada sile wọn.