Faith Adebọla
Gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa nni, Tayọ Odueke, tawọn eeyan mọ si Sikiratu Sindodo ti fi ẹdun ọkan ati imọlara rẹ han lori iku iya rẹ to waye loru mọju ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii.
Lori ikanni Instagiraamu rẹ lori ẹrọ ayelujara, arẹwa obinrin naa sọrọ iwuri nipa mama rẹ, o ni oṣu meji sẹyin loun ṣe ayẹyẹ ọjọọbi mama naa tijo-tayọ, lai mọ pe ọlọjọ ti sun mọ itosi, bẹẹ lo sọ bi iku iya naa ṣe ka a lara to ninu ọrọ aro to kọ sibẹ.
Sindodo kọ ọ sibẹ pe:
“Iya mi, Abiyamọ tootọ, Alabaaro mi.
Aa, Afadurajagun mi, wura ọla mi ti ko ṣee fowo ra, iṣẹlẹ yii lagbara ju fun mi o, o ka mi lara ju o!
Ijẹta ni mo ṣi wa pẹlu yin, ti a rira, ta a jọ sọrọ, hummnn.
Titobi rẹ Ọlọrun Ọba, emi o mọ pe iru eyi n bọ wa.
Omije ẹkun mi o dawọ duro o, ko si le duro, ṣugbọn kin ni mo fẹẹ ṣe? Ko si o.
Mo ṣadura pe ki Olodumare Allah fun yin ni Aljannah Firdaus, ko si ṣe aforiji awọn ẹṣẹ yin.
Ki ẹ sun un ire o.”
Bakan naa tun ni Sindodo lu awọn ololufẹ rẹ lọgọ ẹnu pe wọn ṣeun fun bi wọn ṣe ba oun kẹdun iya oun. O ni, “Gbogbo ẹyin ti ẹ pe mi, tẹ ẹ sare jannajanna de ọdọ mi, tẹẹ wa mi wale, tẹẹ duro ti mi, ẹ ṣe mo dupẹ o. Ti mi o ba gbe ipe awọn kan, ẹ ma binu si mi o, mo maa pe pada to ba ya. Ẹ ṣeun ṣeun, gbogbo wa la maa gbẹyin arugbo wa o, Amin.”
Bẹẹ lo fi awọn ami ifẹ, idaro ati idupẹ saarin awọn ọrọ to kọ naa, o tun rawọ ẹbẹ s’Ọlọrun bo ṣe n daro olokọ to wa a wa saye naa.