Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ, inu aarẹ nla ni agba oṣere tiata nni, KudIrat Odukanmi, tawọn eeyan mọ si Iyabọ Oko, wa. Ara mama naa ko le rara, koda, wọn ti n tọrọ owo ti wọn yoo lo fun itọju rẹ bayii lọwọ awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria nilẹ yii ati loke okun.
Ṣe o ti to ọdun meloo kan ti aisan ti kọkọ gbe Iyabo Oko ṣanlẹ, kinni naa le gan-an nigba naa to jẹ wọn gbe e lọ sorilẹ-ede India lati gba itọju.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu AKEDE AGBAYE lọdun 2019 lo ti ṣalaye pe bi ko ba jẹ pe Ọlọrun fẹran oun ni, oun ko ro pe oun le ye aarẹ naa bo ṣe lagbara to.
Lẹyin igba naa, mama yii gbiyanju lati pada soko ere, o ṣe awọn ere kan, ṣugbọn kedere lo han pe alaafia rẹ ko pe mọ. Apa kan ẹnu obinrin naa ti wọ sẹgbẹẹ, ko si lagbara bo ṣe maa n ṣe nigba to ṣi wa ni abarapaa.
Afi bi iroyin ṣe tun gbode bayii pe aarẹ naa tun ti pada sara Iyabọ Oko, Folukẹ Daramọla-Salakọ, oṣere tiata bii tiẹ lo gbe e jade pe o ti le lọdun marun-un ti aarẹ ti n ṣe Iyabọ Oko, to jẹ awọn ẹbi rẹ, awọn ọmọ ati ẹgbẹ alaaanu toun da silẹ (PARA) lawọn ti n ṣe itọju rẹ nibi ti apa awọn ka a de.
O ni ṣugbọn ni bayii, aisan naa tun ti pada wa ju ti tẹlẹ lọ. Folukẹ ni awọn ọmọ Iyabọ Oko tiẹ tun gbe e lọ siluu oyinbo ni nnkan bii oṣu meloo sẹyin, ṣugbọn bakan naa lọmọ n ṣe ori.
“Ẹ jọọ, a n fẹ iranlọwọ fun Iyabọ Oko, ko sohun to kere ju lati fi ran wa lọwọ. Ọlọrun yoo bu kun ẹyin atawọn ololufẹẹ yin, a o ni i firu ẹ gba a lorukọ Jesu.” Bẹẹ ni Folukẹ Daramọla ṣe kede naa soju opo ayelujara.
Bi ẹnikẹni ba fẹẹ ran oṣere tawọn eeyan tun mọ si ‘Apoti aje’ yii lọwọ, eyi ni akanti ti wọn yoo fowo si 1016578835, Zenith bank. Orukọ akanti naa ni: Passion Against Rape and Abuse(PARA)