Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Yoruba bo, wọn ni ọjọ gbogbo ni ti ole, ṣugbọn ọjọ kan ṣoṣo bayii ni ti olohun, eyi lo ṣe rẹgi pẹlu ogbologboo onijibiti to tun jẹ babalawo, Kẹhinde Ibiloye, ẹni ọdun mẹtalelaaadọta kan, to pe ara rẹ ni oniṣegun ibilẹ.
Iṣẹ iṣegun ibilẹ ni ọkunrin yii maa n sọ pe oun n ṣe to fi maa n gbowo lọwọ awọn eeyan niluu Ado-Ekiti atawọn ilu mi-in kaakiri.
Ṣugbọn aipẹ yii ni ọwọ palaba rẹ ṣegi pẹlu bo ṣe fọgbọn jibiti gba miliọnu mẹwaa naira lọwọ ọkunrin oniṣowo kan, Ogbeni Chisom Alli, pẹlu ileri pe oun yoo ba a tọju iya rẹ to wa ni idubulẹ aisan.
Agbefọba, Inspẹkitọ Bamikọle Ọlasunkanmi, ṣalaye fun kootu pe ọkunrin to pe ara rẹ ni oniṣegun ibilẹ yii fọgbọn gba miliọnu mẹwaa naira pẹlu ileri pe oun yoo ba a tọju iya rẹ to wa ni ipo aisan.
Ẹṣẹ yii ni agbefọba juwe gẹgẹ bii oun to lodi si ofin kẹta to jẹ ofin jibiti ti wọn kọ lọdun 2006.
Agbefọba bẹ kootu pe ki wọn wọn fi ọdaran naa pamọ si ọgba ẹwọn titi ti oun yoo fi ri imọran gba lati ọdọ ileeṣẹ to n gba ni nimọran.
Gbogbo akitiyan ọkunrin naa lati jẹ ki ile-ẹjọ yọnda rẹ lo ja si pabo.
Niṣe ni Onidaajọ Abduhamid Lawal paṣẹ pe ki wọn maa gbe ọdaran naa lọ si ọgba ẹwọn, lẹyin eyi lo sun igbẹjọ naa si ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹwaa, ọdun 2021.