Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ko din ni miliọnu mẹfa naira ti awọn ajinigbe to ji eeyan mẹta gbe ni ṣọọṣi Kerubu ati Serafu to wa ni Ọna-Ara, Oju-Irin, l’Ọbada-Oko, nipinlẹ Ogun, n beere bayii, ti wọn ni bawọn eeyan awọn ẹni tawọn ji gbe naa ko ba tete kowo ọhun wa, ki wọn gbagbe nipa riri wọn mọ laye.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa yii, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, iyẹn lọwọ idaji, lasiko tawọn eeyan n ṣe iṣọ oru ni ṣọọṣi naa.
Ẹnikan to fiṣẹlẹ naa to ALAROYE leti ṣalaye pe Ifẹoluwa Alani-Bello, Adebare Ọduntan ati Mary Oliyide ni orukọ awọn mẹta tawọn agbebọn naa gbe lọ lasiko iṣọ oru ọhun.
O ni wọn ti kan sawọn ẹbi wọn pe miliọnu mẹfa lowo itusilẹ awọn mẹta yii, afi ki wọn san an bi wọn ba fẹẹ foju ri wọn.
Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni loootọ lo ṣẹlẹ, ṣugbọn awọn ikọ ọlọpaa to n ri si ijinigbe nipinlẹ Ogun ti bẹrẹ iṣẹ, bẹẹ si ni wọn ti darapọ mọ awọn ti Ọbada-Oko ti ijinigbe naa ti ṣẹlẹ, ireti si wa pe wọn yoo ri wọn laipẹ.
Oyeyẹmi waa sọ pe ohun tawọn n kilọ rẹ ree o, pe kawọn oniṣọọṣi yee lọọ maa ṣejọsin ninu igbo, ki wọn maa ni iṣọ oru lawọn n ṣe. O lawọn ti kilọ fun wọn pe bi wọn yoo ba tiẹ lọ sori oke eyikeyii fun adura, ki wọn jẹ kọlọpaa mọ, ki wọn le daaabo bo wọn, ohun lo delẹ bayii ti awọn ajinigbe n beere owo tabua yẹn.
Ṣugbọn ọrọ ti ṣọọṣi Kerubu yii ko ti i kuro nilẹ ti iroyin tun fi gbode pe wọn tun ti ji obinrin kan gbe ni ṣọọṣi ‘Light Apostolic Church’, eyi to wa labule Ṣobubi, l’Ọbada-Oko kan naa.
Titi ta a fi pari iroyin yii, awọn to jiiyan gbe ni ṣọọṣi Light Apostolic Church yii ko ti i kan sawọn ẹbi obinrin naa, wọn ko ti i sọ iye ti wọn yoo gba ki wọn too tu u silẹ.